Amọtẹkun yoo di ẹgbẹ afẹmiṣofo lọdun yii- Wolii Okikijesu

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Aposteli Paul Okikijesu, ti ijọ Christ Apostolic Miracle Ministry, ti sọ pe Ọlọrun fi han oun pe ikọ alaabo ilẹ Yoruba, Amọtẹkun, yoo yipada di ẹgbẹ afẹmiṣofo lọdun 2021 yii.

Pasitọ Okikijesu to ṣalaye ọrọ yii lasiko to n sọ asọtẹlẹlẹ ọdun 2021, sọ pe bi ikọ Amọtẹkun ko ba ṣọra lọdun yii, bi wọn ko ba laju wọn silẹ daadaa lati ri  bi nnkan ṣe n lọ, wọn yoo sọ wọn di ẹgbẹ lasan ti ko ni i nitumọ, bẹẹ ni awọn kan ninu wọn yoo di afẹmiṣofo.

Ọpọlọpọ oloṣelu ni awọn agbanipa yoo pa lọdun yii gẹgẹ pasitọ yii ti sọ pe oun gbọ ohun Oluwa.

O ni ẹni ti yoo di aarẹ Naijiria ni 2023 ko tilẹ ti i pa ọkan rẹ pọ boya yoo ṣe e tabi bẹẹ kọ, o ni ṣugbọn Oluwa sọ pe ẹni naa ni yoo di aarẹ.

Leave a Reply