Angẹli to n ṣọ mi yoo binu ti mo ba pari ija pẹlu Ọbasanjọ- Gani Adams

Faith Adebọla, Eko

“Bọrọ ṣe jẹ ni Ọbasanjọ sọ ọ yẹn, ko sọrọ a n pari ija kan. Emi gan-an o ni ija kankan lati pari, tori awọn angẹli to n ṣọ mi aa binu si mi, wọn o ni i fori ji mi ti mo ba fi le pari ija pẹlu Ọbasanjọ.”

Aarẹ Ọna kakanfo ilẹ Yoruba, Ọtunba Gani Adams, lo sọrọ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, nibi ipade pẹlu awọn oniroyin to ṣe nile rẹ to wa l’Ọmọle, lagbegbe Ikẹja, nipinlẹ Eko. Ipade ọhun da lori ero ati awọn aba rẹ lati mu ki eto aabo ilẹ Yoruba ati ti orileede yii lapapọ sunwọn si i.

Nibi ipade naa lo ti dabaa pe ko sọna abayọ forileede Naijiria afi ti atunto ba waye, tori eyi lo maa mu ki ominira iṣejọba wa fun awọn ẹka ijọba gbogbo dipo ti gbogbo agbara fi wa lọwọ ijọba apapọ nikan bayii.

O ni ti atunto ba waye, aa ṣee ṣe lati ni ọlọpaa apapọ (federal police), ọlọpaa ẹlẹkunjẹkun (regional police), ọlọpaa ipinlẹ (state police) ati ọlọpaa ibilẹ (local police), ti gbogbo wọn yoo si jumọ ṣiṣẹ papọ, igba naa leto aabo to gbopọn yoo wa, bii tawọn orileede nla agbaye.

Lẹyin ijiroro naa lawọn akọroyin bi i leere ero rẹ lori ọrọ ti Aarẹ ana, Oloye Oluṣẹgun Arẹmu Ọbasanjọ, sọ, pe iwa rẹ ko ba toun mu, awọn o si le lajọṣepọ kan bii alara, Gani Adams ni loootọ lo yẹ koun fesi si ọrọ ti baba Ẹgba naa sọ, ṣugbọn oun o ni esi kan ju pe oun naa o le pari ija pẹlu rẹ, tori awọn angẹli to n ṣọ oun aa binu toun ba ṣe bẹẹ.

Lọrọ kan, bi aarin awọn mejeeji ṣe wa bayii le wa bẹẹ fungba pipẹ.

Leave a Reply