Anuoluwapo, akẹkọọ Fasiti Ilọrin, gbẹmi ara rẹ 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni akẹkọọ Fasiti Ilọrin, Elijah Jude Anuoluwapo, to wa ni ipele kẹrin (400-level), lẹka imọ ẹkọ ede Gẹẹsi, nile ẹkọ ọhun gbe majele jẹ, to si gba ibẹ lọ sọrun alakeji.

ALAROYE gbọ pe ni kete ti akẹkọọ naa jẹ majele ọhun ni wọn sare gbe e lọ si ileewosan ẹkọsẹ iṣegun oyinbo ti Fasiti Ilọrin (UITH), Ilọrin, ipinlẹ Kwara lati doola ẹmi rẹ, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, eleku ọrun ti polowo, iku ti mu ẹmi ẹ lọ. Wọn ni Anuoluwapọ ti gbiyanju lẹẹmeji ọtọọtọ tẹlẹ lati gbẹmi ara rẹ, ko too wa di pe ala rẹ wa si imuṣẹ lowurọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii.

Ọkan lara mọlẹbi oloogbe ọhun to ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe lati igba ti iya Anuoluwapọ ti ku ni iporuru ọkan ti ba oun gan-an alara, to si ti n gbero lati gbẹmi ara rẹ. Ẹni naa fi kun un pe ṣe ni Baba Aanuoluwapọ pa iya rẹ ti lati igba to ti ni oyun oloogbe naa, to si jẹ pe iyaaya rẹ lo wo o dagba, ki iya naa too ku ọdun to kọja. Wọn ni latigba ti iya naa ti ku ni Aanuoluwapọ ko ti gbadun mọ, to si n fojoojumọ karibọnu, ko too di pe o ṣeku pa ara rẹ ni owurọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, lẹyin to mu majele tan.

Wọn ni Aanuoluwapọ jẹ ẹni to jafafa lẹnu ẹkọ rẹ, to si jẹ ọkan lara awọn to muna doko ju lọ ni ẹka imọ ede Gẹẹsi.

ALAROYE gbọ pe awọn alaṣẹ Fasiti Ilọrin ti mu un lọ si ẹka to n gba ni nimọran nile-ẹkọ ọhun lẹyin to gbiyanju lati gbẹmi ara rẹ lakọkọ.

Leave a Reply