Apaayan ọmọ ẹgbẹ ‘Ẹiyẹ’ ni Ṣẹgun, ibi to ti n sa kiri lọwọ ti ba a n’Ikorodu Faith Adebọla, Eko

Faith Adebọla, Eko

 

 

 

Ti wọn ba n wa oṣikatan tẹsẹ mọrin ẹda, ọkunrin tẹ ẹ n wo fọto ẹ yii wa ninu wọn, Ṣẹgun Agodo ni wọn porukọ ẹ, agbegbe Ikorodu, nipinlẹ Eko, lo n gbe, ṣugbọn bo ṣe ṣika tan, to yinbọn pa awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti wọn jọ n ja lo fẹsẹ fẹ ẹ lọ si adugbo Odongunyan, ibẹ naa lawọn agbofinro ti mu un laaarọ ọjọ Aiku, Sannde yii.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn lo pẹ tawọn ọlọpaa ti n wa Ṣegun, ko si sidii meji ju pe ọwọ ẹ ni wọn n kan nidii awọn iku abaadi to n waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ‘Aiye,’ wọn latamatase ni, ọmọ ẹgbẹ ‘Ẹiyẹ’ si loun, oun lo n yinbọn pa awọn ti wọn jọ n ja.

Wọn ni gbogbo igbiyanju awọn agbofinro lati mu afurasi ọdaran yii lo maa n ja si pabo, tori ki i duro rara to ba ti ṣiṣẹ laabi ọwọ ẹ tan, kia ni yoo ti fẹsẹ fẹ ẹ, ti yoo lọọ sa pamọ sagbegbe Odongunyan to ba ti gbọ pe wọn n wa oun.

Agbegbe Odongunyan ọhun lo wa tẹnikan fi kẹẹfin ẹ nidaaji ọjọ Sannde yii, agbofinro kan ti o wọṣọ lonitọhun, niyẹn ba dọgbọn ta awọn ọlọpaa ti wọn wa lẹka Sagamu Road, lolobo, kia ni DPO teṣan naa ti ko awọn ẹmẹwa ẹ lọ sibẹ, ibi ti Ṣẹgun ti n mura ati jade ni wọn ka a mọ, ni wọn ba fi pampẹ ọba mu un.

Olumuyiwa Adejọbi, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, sọ pe wọn tẹle Ṣẹgun de ile to fori pamọ si l’Odongunyan, wọn tun tẹle e de ile to loun n gbe n’Ikorodu, ibẹ ni wọn ti ba ọpọ awọn nnkan ija oloro to fi n ṣọṣẹ.

Lara awọn nnkan ti wọn ka mọ ọn lọwọ ni ibọn agbelẹrọ to maa n yin lera-lera meji, revolver pistol ni wọn pe e leebo, o si ti rọ ọta ilọpo meje sinu ọkọọkan wọn, wọn tun ba katiriiji ọta ibọn onilọpo mẹrinla ti wọn o ti i yin, aake gbọọrọ kan, awọn ada, ati oogun abẹnu gọngọ to fi n ṣagbara.

Wọn lafurasi ọdaran naa jẹwọ pe loootọ loun n ṣe ẹgbẹ okunkun ‘Ẹiyẹ’, loootọ loun si ti paayan sẹyin, o ni ṣugbọn awọn to ba ṣẹ oun loun maa n pa, ki i kan i ṣe ẹnibọdi.

Ṣa, Ṣẹgun ti balẹ sakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, o ti n ran wọn lọwọ lẹnu iṣẹ iwadii wọn. Wọn ni ibẹ lo maa gba dewaju adajọ laipẹ

Leave a Reply