APC fa ọjọ idibo abẹle wọn sẹyin, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu yii, ni wọn yoo yan oludije funpo aarẹ

Monisọla Saka

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni Akọwe ipolongo fun ẹgbẹ oṣelu APC, Felix Morka, kede fawọn oniroyin pe awọn ti ṣatunṣe si awọn ọjọ ti idibo aarẹ atawọn mi-in yoo waye.
O ṣalaye pe lẹyin ipade pẹlu awọn igbimọ apaṣẹ ẹgbẹ naa lawọn fẹnu ko pe ọjọ kọkandinlọgbọn, si ọgbọnjọ, oṣu Karun-un yii, ni eto idibo abẹle fun ipo aarẹ yoo waye. Eyi wa sẹyin ju ọjọ kọkanlelọgbọn si ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹfa, ti wọn ti kọkọ fẹnu ko si tẹlẹ.
Bakan naa ni ayipada de ba ọjọ ti wọn yoo dibo awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin, awọn aṣoju-ṣofin ati tawọn aṣofin agba pẹlu awọn gomina.
Ṣugbọn akọwe ikede yii ko sọ fawọn oniroyin, ọna ti eto idibo naa yoo gba waye, boya gbangba-laṣaa-ta ni o abi eyi ti onikaluku yoo di tiẹ ni kọrọ, tabi pe wọn yoo fẹnu ko lati fa oludije kan kalẹ. Ohun to kan sọ ni pe gbogbo alakalẹ bi eto idibo naa yoo ṣe waye yoo wa ninu iwe ilana idibo ti wọn yoo fi ranṣẹ sawọn ọmọ ẹgbẹ.
Bakan naa lo ṣalaye pe gbogbo ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lori eto idibo naa fun ileegbimọ aṣoju-ṣofin ati tawọn gomina yoo waye lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun-un, nigba ti ti ileegbimọ aṣofin ati ti sẹnetọ yoo waye lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Karun-un yii.
Igbakeji alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu APC lati apa Ariwa, Abubakar Kyari, ti sọ ṣaaju pe ko din ni eeyan to marundinlaaadọjọ(145) to n dupo gomina ninu ẹgbẹ naa. Ọtalelọọọdunrun o din mẹsan-an (351) lo n dije fun ipo sẹnetọ nigba ti igba mẹfa din mẹta (1,197) n dije fun ileegbimọ aṣoju-ṣofin.
Lara awọn ti wọn ti ra fọọmu ti wọn si ti ko o siwaju awọn igbimọ to n ri si eto idibo ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni, Igbakeji Aarẹ ilẹ yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Aṣiwaju Bọla Tinubu. Awọn yooku ni, Minisita feto irinna nilẹ yii, Rotimi Amaechi, Minisita fọrọ idagbasoke Niger Delta tẹlẹ, Sẹnetọ Godswill Akpabio ati alaga ẹgbẹ awọn gomina nilẹ yii to tun jẹ Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi, Gomina Yahaya Bello ti ipinlẹ Kogi, Ahmed Yerima to jẹ gomina ipinlẹ Zamfara tẹlẹ atawọn mi-in.

Leave a Reply