APC fẹ ki ajọ INEC yi ibo awọn agbegbe kan fun oludije wọn-PDP

Agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu PDP lapapọ, Ọgbẹni Kọla Ologbondiyan, ti pariwo pe awọn ẹgbe APC ti wa le ajọ eleto idibo (INEC) lọrun lati yi awọn ibo agbegbe kan ki iye ibo ti oludije ẹgbẹ APC, Ize-Iyamu, ni le pọ si i. O waa rọ alaga ajọ eleto idibo, lati ma ṣe ṣe ohun ti awọn eeyan yii n fẹ nitori iṣọkan Naijiria.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita ni oru ọjọ Abamẹta, Satide, ti eto idibo naa waye ni wọn ti sọ pe niṣe ni wọn wa le ajọ eleto idibo lọrun lati yii awọn ibo agbegbe ori omi, ki wọn le ṣe afikun ibo ti oludije APC ni nibẹ.

Bakan naa ni wọn ni oju wọn wa nibi esi idibo agbegbe Fugar, ati awọn ati awọn ijoba ibilẹ mi-in to wa ni agbegbe Ariwa Edo.

Ṣaaju ni olori ileegbimọ aṣofin agba nilẹ wa tẹlẹ, Bukọla Saraki, ti rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Edo pe ki wọn joye oju lalakan fi n ṣọri, ki wọn ri i pe wọn duro ti ibo wọn, wọn si ṣe ọrọ naa ni toju tiyẹ ti aparo fi n rina, ki wọn ma baa yi ibo naa mọ wọn lọwọ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Lẹyin ọdun mẹta ti tẹnanti tilẹkun ile pa, adajọ ni ki lanlọọdu lọọ ja a n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Ilọrin paṣẹ ki …

One comment

  1. Ero mi Ni pe ki a ma se gburo ohun to nje Baba Isale Oloselu mo Ni Naijiria wa.😆

Leave a Reply

//ugroocuw.net/4/4998019
%d bloggers like this: