APC fun Ojudu, ọkọ ọmọ Tinubu atawọn mi-in niwee gbele-ẹ l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) nipinlẹ Ekiti ti fun Oludamọran pataki fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Sẹnetọ Babafẹmi Ojudu, ọkọ ọmọ Aṣiwaju Bọla Tinubu, Ọnarebu Oyetunde Ojo, niwee gbele-ẹ.

Awọn to ku ni Dokita Wọle Oluyẹde, Enjinnia Ayọ Ajibade, Ọnarebu Fẹmi Adelẹyẹ, Bunmi Ogunlẹyẹ, Akin Akọmọlafẹ, Bamigboye Adegoroye, Oluṣọga Owoẹyẹ, Dele Afọlabi ati Toyin Oluwaṣọla.

Igbesẹ naa waye lẹyin bii ọsẹ meji ti ẹgbẹ APC l’Ekiti kede pe ki igbimọ ẹlẹni-mẹjọ kan ṣeto bi wọn yoo ṣe fun awọn eeyan ọhun niwee gbele-ẹ lẹyin ti wọn ba sọ tẹnu wọn lori ẹjọ ti wọn n ba ẹgbẹ ṣe nile-ẹjọ giga ilu Ado-Ekiti.

Ninu lẹta gbele-ẹ ti akọwe iroyin ẹgbẹ naa l’Ekiti, Ọnarebu Ade Ajayi, fọwọ si ni wọn ti sọ pe abajade igbimọ iwadii tawọn gbe kalẹ lawọn tẹle, idajọ tawọn si fun awọn mọkanla naa bẹrẹ lati Ọjọruu, Wẹsidee, ana.

About admin

Check Also

Nitori to ni oun yoo fopin si eto aabo ni Borno ati Yobe, PDP Ekiti sọrọ si Fayẹmi

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti Ẹgbẹ PDPipinlẹ Ekiti ti yẹgẹ ẹnu si gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayọde …

One comment

  1. Won si maa FI ona Ile Han an Baba won,nitori nkan ti mun un ori lo si ibo min in,ninu egbe APC

Leave a Reply

//zikroarg.com/4/4998019
%d bloggers like this: