APC kede ilana ti wọn yoo lo fun ibo eto ijọba ibilẹ l’ Ogun

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta     

Ẹgbẹ APC ipinlẹ Ogun ti sọ ọ di mimọ pe ilana eto idibo mẹta ti i ṣe pipa ẹnu pọ fa oludije kalẹ (Consensus), didibo fun ọmọ ẹgbẹ latọwọ awọn oludibo (Direct primary) ati ilana kẹta to ni i ṣe pẹlu awọn eeyan diẹ ti yoo dibo lorukọ ẹgbẹ (Indirect primary) lawọn yoo tẹle lati fi dibo ijọba ibilẹ to n bọ lọna yii.

Akọwe ipolongo ẹgbẹ Onigbalẹ nipinlẹ Ogun, Tunde Ọladunjoye lo sọ eyi di mimọ fawọn akọroyin lopin ọsẹ to kọja nile kan ti wọn n pe ni Presidential Lodge, l’Abẹokuta, nigba ti wọn n ṣepade awọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ APC Ogun.

Ọladunjoye sọ pe ẹgbẹ ti fẹnuko pẹlu awọn olori ẹgbẹ nipa orukọ ati ipo awọn oludije lawọn ijọba ibilẹ kan, lẹyin naa ni wọn yoo lo ilana idibo gbogbo ẹgbẹ tabi tawọn oludije diẹ, iyẹn nibi ti ko ba si ifẹnuko lori oludije wọn.

O ṣalaye pe ipade awọn alẹnulọrọ yii waye lati ri i pe ko si oludije to nawo lọna ti ko tọ, bẹẹ lo ni awọn ti yanju iṣoro awọn ibi ti oludije ti pọ ju ipo kan ṣoṣo lọ.

Bakan naa lo ni ẹgbẹ to n ṣejọba Ogun lọwọ yii , APC, yoo ri i daju pe ibo yii lọ nirọwọ-rọsẹ lai si magomago. O ni gbangba laṣaa ta ni idibo yii yoo jẹ, ko ni i da bii awọn eyi ti wọn ti n ṣe ni kọrọ tẹlẹ.

‘‘Awọn agbaagba ẹgbẹ ti fi da Gomina loju pe ilana fifi ẹnu ko yan ondije dupo ti bẹrẹ. To ba  di Ọjọruu,Wẹsidee, wọn yoo mu iwe orukọ awọn ti wọn fẹnu ko le lori lati dije naa wa. A si lero pe awọn ijọba ibilẹ kan yoo fa oludije kan ṣoṣo kalẹ, nigba ti awọn ti wọn ni ju meji tabi mẹta lọ yoo lo ilana idibo ti gbogbo ọmọ ẹgbẹ yoo fi dibo.’’

Bẹẹ ni Ọladunjoye wi.

Leave a Reply