Jọkẹ Amọri
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni ẹgbẹ oṣelu APC kede pe ko ni i saaye fun awọn oloṣelu ti wọn n ṣiṣẹ ijọba lati dibo lasiko ipade gbogboo wọn ti yoo waye ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta yii. Apẹẹrẹ iru awọn eeyan beẹ ni awọn minisita, kọmiṣanna, awọn oludamọran atawọn alaga ileeṣẹ ijọba.
Ninu atẹjade kan ti igbimọ apaṣẹ ẹgbẹ naa fi sita ti wọn pe akọle rẹ ni; ‘Akiyesi fun awọn oloṣelu ti wọn n ṣiṣẹ ijọba ti wọn yan gẹgẹ bii aṣoju lati dibo.’
‘‘Igbimọ apaṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC ti kede pe gbogbo awọn ti wọn yan gẹgẹ bii dẹligeeti lati kopa ninu idibo ti yoo waye ni ọjọ Abamẹta, ṣugbọn ti wọn jẹ awọn oloṣelu to n ṣiṣẹ ijọba ‘KO NI I DIBO’ nitori ariyanjiyan to wa lori ofin eto idibo ori kẹrinlelọgọrin ẹsẹ kejila, ti ọdun 2020.
‘‘Sibẹ naa, wọn le wa bii oluworan lasiko idibo naa.’’
Tẹ o ba gbagbe, awọn aṣofin ilẹ wa lo ṣofin pe gbogbo awọn oloṣelu ti wọn n ṣiṣẹ ijọba ko yẹ lati maa dibo, tabi ki wọn dibo fun wọn lasiko ti wọn ba fẹẹ yan awọn oloye ẹgbẹ, tabi lasiko idibo apapọ, ayafi ki wọn ti kọwe fipo silẹ ni bii oṣu mẹfa si asiko ti eto idibo naa yoo waye.
Ofin yii wa lara eyi ti wọn ṣe, ti wọn si gbe fun Aarẹ Buhari lati buwọ lu u. Ṣugbọn Aarẹ ni ki awọn aṣofin lọọ ṣayẹwo si i daadaa, ki wọn si gba awọn oloṣelu to n ṣiṣẹ ijọba yii laaye lati dibo, ki wọn si le dibo fun wọn pẹlu, ṣugbọn awọn eeyan naa ni awọn ko ṣe ayẹwo kankan si i.
Ibinu ọrọ naa ni agbẹjọro kan, Nduka Edede, fi gbe ọrọ yii lọ sile-ẹjọ giga ijọba apapọ kan ni Umuahia, nipinlẹ Abia, pe ki awọn adajọ foju agba wo o.
Afi lojiji ti Onidaajọ Evelyn Anyadike dajọ pe ki wọn yọ ofin naa danu.
Igbesẹ yii bi awọn aṣofin ninu. Ipinnu tawọn aṣoju-ṣofin si ṣe lori ọrọ yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, tun lagbara ju tawọn sẹnetọ lọ, tori yatọ si pipẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, wọn tun lawọn maa fẹjọ adajọ to paṣẹ pe ki wọn pa ofin kẹrinlelọgọrin yii rẹ sun igbimọ to n ri si ọrọ awọn adajọ, National Judicial Council (NJC), wọn lawọn o nifẹẹ si aṣẹ to pa, wọn laṣẹkaṣẹ gbaa ni, ati pe bawo lo ṣe le paṣẹ ta ko ileegbimọ aṣofin bẹẹ, lai jẹ pe orukọ awọn wa lara olujẹjọ ninu ẹsun yii. Wọn lo jọ pe agbara n pa adajọ naa bii ọti, tabi iromi to n jo lori omi ni, boya onilu rẹ wa nisalẹ odo, awọn si fẹ ki NJC ba awọn tan ina wo idi ẹjọ ati aṣẹ naa.
O jọ pe lati ma jẹ ki ẹgbẹ APC ko si galagala ofin lẹyin-o-rẹyin ni wọn ṣe yaa kuku paṣẹ pe ki awọn ti wọn oloṣelu to n ṣiṣẹ ijọba yii ma kopa ninu eto idibo gbogbogboo ti yoo waye naa.