Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ẹgbẹ awọn olukọ ipinlẹ Ekiti ti bẹrẹ si i da apo meji aabọ Naira lati gba akẹgbẹ wọn, Arabinrin Alice Owoniyi, to wa lọdọ awọn ajinigbe silẹ.
Owoniyi to jẹ olukọ nileewe alakọọbẹrẹ Saint Paul’s Primary School, Ikọle Ekiti, lawọn ajinigbe ji gbe pẹlu awọn mẹrin miiran loju ọna to lọ lati Ikọle si Ayebode Ekiti, lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Ẹnikan to jẹ olukọ ti ko fẹ ki wọn darukọ oun to ba ALAROYE sọrọ sọ pe awọn ajinigbe naa ti kan si awọn mọlẹbi olukọ naa, ti wọn si bere aadọta miliọnu naira.
Olukọ naa sọ pe nọmba ifowopamọ ọkọ olukọ naa to jẹ ti ileefowopamọ First bank ni wọn fi ranṣẹ sawọn olukọ naa ki wọn le fi da owo itusilẹ olukọ ẹgbẹ wọn naa.
Bakan naa ni lẹta kan ti wọn fi ranṣẹ si ori ẹrọ ayelujara gbogbo awọn olukọ to wa ni ijọba ibilẹ Ikọle ti wọn n pe ni (Ikole LG WhatsApp platform) ti wọn fi ṣọwọ si awọn oniroyin sọ pe.
“Awa olukọ ijọba ibilẹ Ikọle n bẹ gbogbo awọn ọmọ ẹlẹgbẹ wa ki wọn doola ẹmi ẹnikan ninu wa, nitori awọn ajinigbe yii ti n halẹ lati gba ẹmi olukọ yii.
“Ẹ jọwọ, ẹyin eeyan mi, ẹ jẹ ka doola ẹmi obinrin olukọ yii, awọn ajinigbe yii ti sọ pe awọn yoo gba ẹmi rẹ ti wọn ba ko tete ri owo ti wọn beere. Eleyii to buru nibẹ ni pe ni gbogbo igba ti awọn ajinigbe naa ba ti pe lati beere owo, niṣe lawọn n gbọ igbe obinrin naa.”
“Arabinrin Owoniyi n bẹ gbogbo yin, a gbọdọ sa ipa wa ki a ri i pe o yọ lọwọ iku ojiji yii. Ju gbogbo ẹ lọ, gbogbo ẹgbẹ olukọ ijọba ibilẹ Ikọle n bẹ awọn olukọ ileewe alakọọbẹrẹ to wa nijọba ibilẹ yii ki wọn bẹrẹ si i da apo meji aabọ Naira, ka le gba ọmọ ẹgbẹ wa yii silẹ.
“Gbogbo ẹlẹgbẹ mi, mo ri igbesẹ yii gẹgẹ bii ọna kan pataki ti a le fi ran obinrin yii ati idile rẹ lọwọ, ki Ọlọrun san an fun wa lọpọlọpọ.
“Ki gbogbo wa gbiyanju lati fi lẹta yii ranṣẹ si awọn ẹgbẹ wa miiran to jẹ olukọ, awọn ajinigbe ti fun wa ni wakati diẹ, ẹ jọwọ, ẹ ran idile yii lowo pẹlu ohun ti agbara yin ba ka.”
Nigba to n sọrọ lori ọrọ naa, Alaga awọn ẹgbẹ olukọ nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Ọkẹ Emmanuel, sọ pe loootọ lawọn olukọ kan nijọba ibilẹ Ikọle n da owo ki wọn le gba obinrin naa silẹ ni akata awọn ajinigbe naa.
O ṣalaye pe igbesẹ ati aṣẹ naa ko wa lati ọdọ awọn alaṣẹ ẹgbẹ olukọ nipinlẹ naa, ṣugbọn awọn ẹgbẹ olukọ nijọba ibilẹ Ikọle ni wọn ṣe eyi lati ran mọlẹbi arabinrin naa lọwọ ko le bọ ninu igbekun awọn ajinigbe naa.
Alaga ẹgbẹ olukọ yii ṣalaye pe awọn ti fi iṣẹlẹ naa to ijọba ipinlẹ Ekiti leti, awọn paapaa si ti fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti.
Ṣugbọn Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe wọn ko ti i fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti.