Faith Adebọla
Ọkan lara awọn oniṣegun oyinbo, Ọjọgbọn Dokita Ṣokunle Sunday Ṣoyẹmi, to lewaju awọn dokita ẹlẹgbẹ rẹ ti wọn ṣayẹwo si oku Oloogbe Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, tawọn eeyan mọ si Mohbad, ti sọ nnkan iyanu kan to ri nibi saare ti wọn ti lọọ hu oku ọmọkunrin naa fun ayẹwo.
Ọjọgbọn Ṣokunle sọrọ yii lasiko to n tẹ pẹpẹ abọ iwadii ohun to ṣokunfa iku oloogbe naa ni kootu akanṣe ti wọn ti n ṣewadii ọhun, iyẹn Corona Court of Inquest, eyi to wa ni Candide Johnson Courthouse, laduugbo Ita-Ẹlẹwa, niluu Ikorodu, nipinlẹ Eko, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Karun-un, ọdun 2024 ta a wa yii.
Ẹ oo ranti pe ọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023, ni Oloogbe Mohbad ku lojiji, ti wọn si sinku rẹ lọjọ keji si agbegbe Igbogbo, niluu Ikorodu.
Amọ latari awuyewuye ti iku ati isinku rẹ ọhun mu lọwọ, eyi to fa ọpọlọpọ iwọde ati ifẹhonuhan tawọn ololufẹ rẹ ṣe kaakiri awọn ipinlẹ kan, ileeṣẹ ọlọpaa tẹsẹ bọ ṣokoto iwadii, wọn si lọọ hu oku oloogbe naa logunjọ, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 ọhun.
Dokita Ọjọgbọn Ṣokunle Sunday Ṣoyẹmi, to jẹ olukọ agba ni fasiti ipinlẹ Eko, Lagos State University (LASU), to si tun jẹ ogbontarigi nidii ṣiṣe iwadii ijinlẹ si oku lati mọ ohun to ṣokunfa iku ẹnikẹni sọ pe lọjọ tawọn lọọ hu oku ọhun fun ayẹwo, ohun to jẹ kayeefi ni pe niṣe lawọn ba okiti okuta lori saare naa, tawọn si tun ba a lori posi.
“Nigba ta a debẹ, okuta nla nla rẹpẹta la ba lori saare Oloogbe. A ni lati kọkọ ko awọn okuta rẹpẹtẹ naa kuro na, ka too le bẹrẹ si i gbẹlẹ lọọ kan posi ti wọn fi sin in. Okuta naa pọ debii pe fun bii wakati mẹrin, okuta la kan n ko ṣaa.
“Nigba ta a si jaja ko o tan, ta a n gbẹnlẹ, bo ṣu ku diẹ ka kan posi, okuta la tun ri. O ya mi lẹnu, tori mi o ri iru nnkan bẹẹ ri laye mi.”
Dokita yii tun sọrọ lori posi ti wọn fi sin Mohbad, pe posi yẹbuyẹbu kan ni. O ni “igi ti wọn fi kan posi oloogbe naa ki i ṣe ojulowo rara. Awọn igi funfun kan bayii ti Yoruba n pe ni ‘sọ-mi-dọlọrọ’ ni. Gbogbo posi naa lo ti wogba, ti awọn igi rẹ si ti fa ya, ba a si ṣe n gbiyanju lati gbe e lo n ya mọ wa lọwọ. Ki i ṣe posi gidi kan.”
Niṣe ni gbogbo kootu naa kun hunnnn pẹlu iyanu nigba ti Dokita Ṣoyẹmi n sọrọ yii. Bẹẹ lawọn kan n darukọ ọkan lara awọn ọrẹ Mohbad, pe oun lo wa nidii iṣẹkiṣẹ naa, wọn ni Darocha to jẹ amugbalẹgbẹẹ oloogbe ni, tori oun lo lọọ ra posi ti wọn fi sin in. Amọ labẹlẹ labẹlẹ ni wọn n sọ ọ, tawọn mi-in si n fika sẹnu pẹlu iyanu.
Ohun iyanu mi-in ti Dokita yii tanmọlẹ si ninu alaye rẹ ni ti ọrọ ẹjẹ ti wọn ni wọn ba ninu saare Mohbad. Awuyewuye yii gbode kan lasiko naa, pẹlu fidio ati fọto loriṣiiriṣii, eyi to mu kawọn eeyan kan sọ pe afaimọ ni ki i ṣe alaaye ni Mohbad nigba ti wọn sin in, wọn ni boya ko ti i ku tan ti wọn fi sin in, tori ẹjẹ naa ṣi pupa, o si tuntun.
Amọ Ọjọgbọn Ṣoyẹmi sọ pe eyi ki i ṣe ootọ rara pẹẹ. O ni: Ni ti awọn ti wọn n sọrọ ẹjẹ nibi saare Mohbad, ohun ti wọn n ya fidio ati fọto rẹ kiri bii ẹjẹ ki i ṣe ẹjẹ rara o. Ilẹ alamọ ni ibi ti wọn sinku oloogbe si, a oo si ranti pe asiko ti ojo wẹliwẹli n rọ lọwọ ni wọn sin in. Lọjọ naa, ojo ṣan amọ pupa to da bii ẹjẹ si apa ibi kan ninu saare naa, ipa amọ pupa yii lawọn kan ri labẹ posi, ti wọn si n gbe e kiri ori ẹrọ ayelujara pe wọn ri ẹjẹ. Ko si ootọ ninu iyẹn. Mohbad ti ku fin-in-fin-in ki wọn too sin in, ayẹwo naa si fidi eyi mulẹ, tori bi ko ba ti i ku ni, awọn nnkan ta a ṣayẹwo si iba jẹ ka mọ eyi.”
Bẹẹ ni dokita to loun ti wa nidii iṣẹ ṣiṣayẹwo si oku fun ohun to le logun ọdun yii, sọ o.