Ara Muyiwa Ademọla ko ya o

Ara gbajumọ oṣere nni, Muyiwa Ademọla ko ya o. Bi a si ti n wi yii, ọsibitu ni ọkan pataki ninu awọn oṣere ọmọ Yoruba naa wa. Funra rẹ lo gbe e si ori ẹrọ abẹyẹwo, instagram, rẹ, ohun to si kọ sibẹ ni pe ojojo n ṣogun, ara ogun ko le. O ni oun ko kọ iru eleyii sita ri, ṣugbọn bi kinni naa ṣe wa lasiko yii yẹ ki oun wi, nitori awọn ọriṣiriiṣ iṣẹ to wa niwaju oun. Muyiwa Ademọla ya fọto ara rẹ, nibi ti wọn ti so omi mọ ọn lapa gan-an si ni.

Ni gbara ti kinni naa jade ni awọn eeyan ti bẹrẹ si pariwo, ti awọn eeyan si n sọ pe iru ki leleyii, ti kaluku awọn ololufẹ rẹ si n ṣadura fun un. Ṣugbọn aya awọn eeyan mi-in ja debi pe wọn ro pe aisan nla kan lo n ṣe Muyiwa, ti wọn si bẹrẹ si i ronu, ti awọn mi-in n tori ẹ gbarayilẹ pe kinni kan ko ni i ṣe e. Loootọ si ni o, bi eeyan ri fọto rẹ nibi ti wọn ti ki abẹrẹ bọ ọ lọwọ, ti wọn so omi mọ ọn lapa yii, aya yoo ja oluwa rẹ.

Ṣugbọn ọkan ninu awọn to sun mọ ọn daadaa, Wuraọla, ba awọn oniroyin Punch sọrọ nigba ti pipe ati ariwo naa pọ ju, ti kaluku saa n fẹẹ mọ ohun to n ṣe Muyiwa Ademọla gan-an. O ni aisan naa ki i ṣe eyi to le dan-in dan-in kan o, o n i iṣẹ ojoojumọ ti Muyiwa n ṣe lo da aisan si i lara, nitori ki i ri aaye sinmi rara.

“Ẹ wo o, ki ṣe ohun kan to le o jare. O gbọdọ wa nibi to wa yẹn fun odidi ọsẹ kan ni. Ki i fun ara rẹ nisinmi rara, bi ko si lori foonu, yoo wa nibi to ti n ṣiṣẹ, yoo sa maa ri kinni kan ṣe ṣaa ni, bẹ ara n fẹ isinmi. Nitori ko le sinmi yẹn gan-an ni wọn ṣe da a duro, ko le gba agbara rẹ pada, ki i se aisan kan to la okun ẹmi lọ!” Bẹẹ ni Wuraọla wi, eleyii si fi ọkan awọn eeyan balẹ pe aarẹ ara lasan lo mu Muyiwa Ademọla, ki i ṣe aisan kan gidi.

Leave a Reply