Aramọkọ-Ekiti ni Waheed atawọn ọrẹ ẹ ti ja mọto gba, Eko lọwọ ti tẹ wọn

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Yoruba bọ wọn ni ọjọ gbogbo ni tole, ṣugbọn ọjọ kan ni ti olohun, eyi lo ṣẹ mọ awọn ọrẹ mẹta kan, Agboọla Kunle, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn (31) Balogun Waheed, ẹni ogun ọdun (20), Taiwo Islamia, ẹni ọdun mọkandinlogun (19), ati Adele  Samuel, ẹni ọdun mẹtalelogun, ti wọn lọọ ji mọto ni ilu Aramọkọ Ekiti, nipinlẹ Ekiti, ṣugbọn ti ọwọ pada tẹ wọn ni ilu Eko.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, ṣalaye fun akọroyin wa pe awọn afurasi ti wọn jẹ ogbologboo ole yii ni wọn ti n da awọn eeyan ipinlẹ naa laamu lati ọjọ to pẹ.

O sọ pe lọjọ ti ilẹ mọ ba oloro awọn eeyan naa, ẹka kan to n gbogun ti awọn to ba ji ọkọ gbe ti kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ṣẹṣẹ ṣagbekalẹ rẹ ni wọn tọpinpin awọn ẹlẹgiri naa lọ si ipinlẹ Eko, nibi ti ọwọ ti tẹ wọn.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni awọn afurasi adigunjale naa ja ọkọ akero kan gba ni Aramọkọ-Ekiti, wọn si tun gba foonu kan lọwọ ẹni to ni ọkọ naa, ni wọn ba sa lọ si ilu Eko. Lasiko ti awọn ọlọpaa n tọpinpin awọn adigunjale naa pẹlu iṣẹ iwadii wọn ni wọn kẹẹfin pe ilu Eko ni wọn wa. Ni wọn ba wa wọn lọ, ibẹ naa ni awọn agbofinro ti gba ọkan ninu wọn mu, ti wọn si ba ẹrọ ilewọ ti wọn gba lọwọ dẹrẹba naa lọwọ rẹ.

Alukoro ṣeleri pe awọn ko duro rara, iwadii n lọ lọwọ lati ri i pe awọn ri awọn to ku mu, bẹẹ lo ni laipẹ lawọn yoo ri mọto ti wọn ji gbe naa gba pada nibikibi ti wọn ba gbe e si.

Leave a Reply