Arapaja di Igbakeji Alaga ẹgbẹ PDP niha Guusu

Faith Adebọla

 Igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan, Ọgbẹni Taofeek Arapaja, ti jawe olubori sipo Igbakeji Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ni Guusu ilẹ wa, o si fẹyin alatako rẹ toun naa jẹ gomina ipinlẹ Ọsun tẹlẹ ri, Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla, janlẹ.

Iṣẹlẹ yii waye lowurọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwaa yii, lasiko ti wọn n ka abajade ibo tawọn aṣoju to pesẹ sibi apero apapọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ọhun di, lati mọ ẹni to maa wa nipo igbakeji alaga ẹgbẹ lagbegbe Guusu Naijiria.

Ṣaaju ni awuyewuye ti wa pe ki ẹnikan ninu awọn ondije fun ipo Igbakeji alaga naa juwọ silẹ fun ẹnikeji, ko le dọgba pẹlu eto ti ẹgbẹ PDP ṣe lori awọn ipo ijoye ẹgbẹ yooku, leyii ti ko si alatako kankan, ayafi ipo Igbakeji alaga Ariwa.

Ṣugbọn ko sẹni to juwọ silẹ laarin Arapaja, ti Gomina Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ jẹ igi lẹyin ọgba fun gbagbaagba, ati Ọmọọba Oyinlọla ti gbogbo eeyan bọwọ fun bii ọkan lara awọn agba ẹgbẹ PDP. Eyi lo mu kọrọ naa di didibo le lori.

Lẹyin idibo, gẹgẹ bi Gomina Ahmadu Umaru Fintiri tipinlẹ Adamawa ṣe kede abajade rẹ, Arapaja ni ibo ẹgbẹrun meji o le mẹrin (2004), nigba ti Oyinlọla ni ibo ẹẹdẹgbẹrin o le marun-un (705), ninu ẹgbẹrun mẹta aabọ ati mọkanla (3511) aṣoju ti wọn pesẹ sibi eto naa.

Aropọ ibo marunlelọgọjọ (165) ni wọn ni ko wulo, wọn da a nu bii omi iṣanwọ ni, awọn aṣoju ojilelẹgbẹta din mẹta (637) ni wọn ko dibo lasiko idije ọhun.

Pẹlu eyi, Taofeek Arapaja ni Igbakeji alaga ẹgbẹ PDP niha Guusu ilẹ wa.

Leave a Reply