Aree ti ilu Iree tuntun: Awọn afọbajẹ ko yọju sibi ipade tijọba Ọṣun pe

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ipade ti wọn pe lati yan ọba tuntun fun ilu Iree, nijọba ibilẹ Boripẹ, nipinlẹ Ọṣun, fori ṣanpọn latari bi ko ṣe si afọbajẹ kankan to yọju sibẹ.

Awọn afọbajẹ ọhun ni ijọba ibilẹ idagbasoke Ariwa Boripẹ nipasẹ Ọga agba kan, D. Oyelakin, kọ lẹta si pe wọn yoo pade l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kọkanla yii lati yan Aree tuntun.

Ṣugbọn a gbọ pe ko si afọbajẹ kankan to yọju sibi ipade naa, dipo ki wọn lọ, ṣe ni wọn kọ lẹta sijọba ipinlẹ Ọṣun labẹ asia Aree-in-Council, lori igbesẹ ti wọn sọ pe o lodi si aṣa ilu naa ti awọn kan fẹẹ gbe.

Awọn afọbajẹ naa ṣalaye pe ṣe ni awọn kan fẹẹ fi agbara yan ijoye alakanṣe iṣẹ (Warrant chief) fun awọn lori ijokoo yiyan ọba tuntun naa.

Ninu lẹta naa ti wọn fi ṣọwọ si alaga ijọba ibilẹ agbegbe idagbasoke Boripẹ, kọmiṣanna fun ọrọ oye-jijẹ, ọga agba funleeṣẹ ọlọpaa lorileede yii ati kọmiṣanna funleeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, ni wọn ti fẹsun kan ijọba ibilẹ naa.

Wọn ni, “Lati le dena wahala ati idarudapọ niluu Iree la ṣe gbe igbesẹ yii. Ilana to wa nilẹ ni pe ti a ba fẹẹ yan ijoye alakanṣe iṣẹ, ojuse awa afọbajẹ ni lati mu ijoye kan ti yoo di alafo naa.

“Nigba ti awọn afọbajẹ ko ba waa ri ijoye kankan fa kalẹ nijọba too le lo ọgbọn wọn lati yan ijoye pataki naa. A ti mu Oloye Ọdọka Oke Eesa ti ilu Iree to jẹ ijoye to ga ju laarin awon oloye, o si ti gba lati ṣiṣẹ naa. A nigbagbọ pe alaafia to ti wa niluu Iree ko ni i di fiafia.”

Ṣugbọn nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alaga ọhun, Azeez Ọladẹjọ, sọ pe igba kẹta niyẹn ti awọn afọbajẹ yoo kọ jalẹ lati fara han nipade lati yan ọba tuntun fun ilu Iree.

Leave a Reply