Arẹgbẹṣọla, Amosun lo mu mi de ọdọ Buhari

Ọrẹoluwa Adedeji

Yatọ si ohun ti awọn kan n sọ kiri pe Aṣiwaju Tinubu lo fa Igbakeji Aarẹ, Yẹmi Ọṣinbajo, le Buhari lọwọ fun ipo naa lọdun 2015, ọkunrin naa ti sọ pe ọrọ ko ri bẹẹ o. O ni Gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Raufu Arẹgbẹṣọla, ati ojugba rẹ to jẹ gomina Ogun nigba kan, Ibikunle Amosun, lo mu oun lọ sọdọ Buhari.
O sọrọ naa lasiko to n ṣinu pẹlu awọn akọroyin niluu Abuja l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Igbakeji Aarẹ ni Rauf Arẹgbẹṣọla lo kọkọ sọ fun oun pe wọn ti yan oun gẹgẹ bii Igbakeji Aarẹ ilẹ wa lọdun 2015. O ni, ‘‘Mo n ṣiṣẹ lori ẹjọ kan lọwọ ni ni Paniel Apartments, niluu Abuja, lọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2014, ti mo gba ipe lori aago mi ni nnkan bii aago kan oru lati ọdọ Rauf Arẹgbẹṣọla pe awọn n bọ niluu Eko lati waa gbe mi. Mo sọ fun wọn pe mo wa niluu Abuja, o si sọ pe ‘o daa bẹẹ, nitori wọn ti yan ọ gegẹ bii igbakeji aarẹ ilẹ wa’, mo si beere pe ṣe bi ẹ ṣe maa n yan eeyan naa niyẹn.’’

Ọṣinbajo ni lẹyin toun pari ẹjọ ti oun ni ni kootu lọjọ naa, oun pada si yara ti oun gba, loju-ẹsẹ loun ṣi fila ofin ti oun wọ, ti oun si wo o pe, eyi ni igba ikẹyin ti oun maa de wiigi ọhun gẹgẹ bii agbẹjọro.
Igbakeji Aarẹ yii ni Arẹgbẹṣọla ati Amosun ni wọn pada mu oun lọ sọdọ Buahri gẹgẹ bi akọroyin Premium Times ṣe ṣalaye. O ni oun n ṣe alaye yii fun awọn akọroyin naa lati mọ pe, laarin iṣẹju kan ni ayipada le de ba igbesi aye eeyan.
O ni latigba to ti pẹ loun ti gbagbọ, ti oun si n ṣiṣẹ fun bi Naijiria yoo ṣe dara. Igbakeji Aarẹ naa ni eyi lo fa ipinnu oun lati dije dupo aarẹ lọdun 2023 lati le mu iyatọ wa.
O fi kun un pe eeyan perete lo ni ẹkọ ati iriri ti oun ni. Bẹẹ lo ni oun ti ṣabẹwo si ọdọ ọpọlọpọ ẹlẹgbẹjẹgbẹ latigba ti oun ti fi ipinnu oun lati dupo han. Lara wọn ni awọn gomina, awọn aṣoju ẹgbẹ ti yoo dibo abẹle, awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu.
O fi kun un pe awọn akọroyin ni ẹgbẹ akọkọ ti oun pe lati ṣinu pẹlu ti ki i ṣe lara awọn ti yoo dibo lasiko idibo abẹle.
Bakan naa ni alaga awọn akọroyin, Ọgbẹni Chaffe gboriyin fun Ọṣinbajo pẹlu ajọṣepọ to daa to ni pẹlu awọn akọroyin latigba to ti wa nipo Igbakeji Aarẹ.

Leave a Reply