Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Kọmiṣanna tẹlẹ fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Adebayọ Adeleke, ti sọ pe orukọ Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ti kuro lara awọn gomina to ti inu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) jade.
Adeleke, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Banik, sọ pe Arẹgbẹṣọla yọnda ara rẹ ki wọn lo o ta ko ẹgbẹ APC l’Ọṣun, o si ṣe ijamba nla fun ẹgbẹ naa, o ni ọrọ rẹ da bii ti ẹni to pọnmi lodo tan, to waa da odo ru.
Nibi ipade awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni Aarin Gbungbun Ọṣun, eyi to waye ni sẹkiteriati wọn to wa ni Ogo-Oluwa, niluu Oṣogbo, lo ti sọrọ naa.
O ni loootọ lo wa ninu akọsilẹ ipinlẹ Ọṣun pe Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Ọṣun, ṣugbọn pẹlu iwa agbẹyinbẹbọjẹ to hu, o ti ge ara rẹ kuro lara ẹgbẹ naa, gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ si mọ pe ki i ṣe ara wọn mọ.
Adeleke fi kun ọrọ rẹ pe ko sẹnikankan nipinlẹ Ọṣun ti ko mọ bi Arẹgbeṣọla ṣe paṣẹ fun awọn ọmọlẹyin ati abẹṣinkawọ rẹ lati ṣiṣẹ ta ko aṣeyọri ẹgbẹ APC lasiko idibo aarẹ, idibo gomina atawọn yooku to waye kọja.
O ni bakan naa ni gomina tẹlẹ ọhun fi ẹgbẹ naa ṣe yẹyẹ ni kete ti wọn lulẹ nile-ẹjọ to ga ju lọ lorileede yii.
Banik ṣalaye pe ọmọ ẹgbẹ to ba farajin, paapaa, ẹni to jẹ gomina tẹlẹ, to si tun jẹ minisita labẹ ẹgbẹ to wa ko gbọdọ hu iru iwa ti Arẹgbẹṣọla hu ọhun.
O waa ke si Arẹgbẹṣọla lati lọ tuuba lọdọ awọn adari ati oloore rẹ, Aarẹ Bọla Tinubu, to ba ṣi fẹ ki wọn maa fi ọwọ to yẹ wọ ọ ninu ẹgbẹ APC.