Jọkẹ Amọri
Loootọ ni ọkunrin naa ko fidi rẹ mulẹ pe nitori ohun ti oun ṣe lọ si ile Agba-oye Ibadan nni, Rashidi Ladọja, niyẹn, ṣugbọn awọn to mọ bo ṣe n lọ ti n gbe e pooyi ẹnu pe ọkunrin to ti figba kan ṣe gomina Ọṣun, to si tun jẹ minisita fun ọrọ abẹle nilẹ yii ko tori ohun meji lọọ ri Ladọja ju nitori Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Yẹmi Ọṣinbajo, lọ.
Wọn ni Arẹgbẹ lọọ ri ọkunrin oloṣelu Ibadan naa lati beere atilẹyin rẹ fun Igbakeji Aarẹ ilẹ wa ti oun naa n gbaradi lati jade dupo aarẹ Naijiria.
Aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni Rauf Arẹgbẹṣọla ati ọmọọṣẹ rẹ, Bọla Ilọri, lọ si ile Ladọja to wa ni Ondo Street, Bodija Estate, niluu Ibadan. Bo si ti debẹ lo wọle ipade pẹlu agba oṣelu naa, odidi wakati meji ni wọn fi tilẹkun mọri sọrọ.
Ipade yii waye ni ọjọ kẹta ti Asiwaju Bọla Tinubu paapaa ṣabẹwo si agba oṣelu naa, to si beere fun atilẹyin rẹ fun ipo aarẹ to fẹẹ du.
Lẹyin ipade naa la gbọ pe Ladọja sin awọn alejo rẹ de idi mọto, ti wọn si lọ.
Awọn to mọ bo ṣe n lọ sọ pe Ọṣinbajo ni Arẹgbẹṣọla n ṣatiẹyin fun lati dupo aarẹ Naijiria, wọn ni tirela ti gba aarin oun ati ọga rẹ, Aṣiwaju Tinubu kọja, ọrọ naa si ti di konko jabele.