Arẹgbẹṣọla, fi Oyetọla lọrun silẹ, jẹ ko raaye ṣejọba l’Ọṣun – Oyinlọla

Idowu Akinrẹmi, Ikire

Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla ti i ṣe gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, ti rọ Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ko gba alaafia laaye, ki gomina ipinlẹ naa, Gboyega Oyetọla, le raaye ṣakoso daadaa l’Ọṣun.

Gomina tẹlẹ yii sọrọ ọhun pẹlu bi awọn mejeeji ṣe n gbaradi lati ṣe ayẹyẹ ọtọọtọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu yii. Oyinlọla ninu ọrọ ẹ to ba iwe iroyin ALAROYE sọ rọ Arẹgbẹṣọla, lati sun eto tiẹ si ọjọ miiran, ki wahala to ṣee ṣe ko bẹ silẹ le ma waye.

O fi kun un pe, lọdun 2003 toun di gomina, Oloye Bisi Akande ko fi igba kankan daamu ijọba oun ri. Bẹẹ naa ni oun ko daamu Arẹgbẹsola lasiko ìṣèjọba rẹ, ninu eyi to ti lo ọdun mẹjọ, bo tilẹ jẹ pe o ni ọna to gba fi le oun nile ijọba.

O ti waa rọ Arẹgbẹṣọla ko jawọ ninu iwa yoowu to ba le mu ki ìṣèjọba nira fun Oyetọla, ki ipinlẹ Ọṣun ma baa tun ko sinu wahala miiran lẹyin iṣoro koronafairọọsi ati rogbodiyan to sẹlẹ lasiko iwọde ta ko SARS to ṣẹṣẹ kasẹ nilẹ.

One thought on “Arẹgbẹṣọla, fi Oyetọla lọrun silẹ, jẹ ko raaye ṣejọba l’Ọṣun – Oyinlọla

  1. imonran mi nipe, ki gomina oyetola mongba eesu laye koranti ipile ohun ati oga re, ki aregbesola naa monpe ti abafun eniyan ni eran sin oyekafi okun re sile, ki awon mejeji ronu pe awon eniyan tolese dada ju tiwon loba po ni ipinle osun,amon anu-olohun niwon ri gba.

Leave a Reply