Faith Adebọla
Gbajugbaja oṣere tiata ilẹ wa kan, Arẹmu Afọlayan, ti wọn epe nla fawọn oloṣelu latori Aarẹ ilẹ wa, o lawọn ni wọn mu ipọnju ba Naijiria, awọn si ni wọn ko jẹ ki orileede naa goke agba bo ṣe yẹ.
Ninu fidio kan to gbe sori opo ayelujara Instagraamu rẹ logunjọ, oṣu Karun-un yii, ọkunrin naa wa ninu gbọngan nla minringindin kan nilu oyinbo lọhun-un, lo ba tẹnu bọ ọrọ, o ni:
“Tọmọ-tọmọ, taya-taya, tẹbi-tẹbi, titi kan awọn ọmọ to jẹ gẹlfurẹndi yin, ati awọn iyawo yin ti wọn n ṣina nita, ẹ maa jona, ẹ maa ṣoriburuku. A mọ pe ẹ n dojukọ purobulẹẹmu naa o, ko si oṣiṣẹ ijọba kan ti ko ni purobulẹẹmu to n dojukọ, ṣugbọn iṣoro yin maa di ilọpọ ilọpo lọna biliọnu ni tẹ ẹ o ba ṣe ilu ko dara bii eyi. “Gbogbo purobulẹẹmu yin, a mọ pe ẹ maa n ṣoṣi gbẹyin aye yin ni, ẹ maa n rare gbẹyin ni, latori alaga ijọba ibilẹ, titi dori purẹsidẹnti. Gbogbo ẹnikẹni to ba ti n ko wahala ba ọmọ Naijiria, ti ko jẹ kile aye wọn dara, to n jẹ ki wọn maa sa hilahilo kaakiri, to n jẹ ki wọn daamu, to n jẹ ki wọn laalaṣi, gbogbo wọn lo maa ṣofo, lagbara Ọlọrun, ẹ maa ṣoriburuku.
“Ipinlẹ lasan ni ibi ta a wa yii o, odidi orileede ni Naijiria, owo eeyan marun-un lasan maa kọ iru ibi taa wa yii. Oloriburuku ni yin, ẹẹ maa ṣoṣi, ẹ waa n ra jiipu kiri.
“Deborah ku, iwọ Buhari, oo ṣabẹwo si wọn, oo tiẹ sọrọ nipa ẹ. Ṣugbọn Sheikh Dubai ku, ẹni to ni ala rere fun ọjọ-ọla ju ẹ lọ, ẹni ti igbesi aye ẹ daa ju tiẹ lọ, ti igbesi aye rẹ daa ju ti gbogbo ọba Naija lọ, o ku, iwọ wa, o waa ki i.
“Bẹẹ si ree, bi aarẹ Dubai ṣe ku, laarin wakati marun-un si mẹfa, wọn ti forikori, wọn ti yan ẹlomi-in sipo. Bo ba jẹ tiyin ni, ẹ ṣi maa maa mu ankara kiri, ẹ maa fẹẹ ya aworan sara ẹ, oloriburuku ni yin, ẹ maa ṣofo. Titi kan gẹlifurẹndi tẹ ẹ n ba sun ni o, awọn ọmọge to yẹ ki wọn fun yin ni majele jẹ, ti ẹ n gbe kiri, gbogbo yin pata lẹ maa ṣofo danu. Ile ree, ṣebi ilu niyi”
Bi Arẹmu ṣe ju fidio yii sori ikanni ẹ lawọn eeyan ti n kan saara si i loriṣiiriṣii, wọn ni ododo ọrọ lo sọ, awọn mi-in si n ṣe “amin,” si ọrọ ẹ, wọn ni bẹẹ ni ko ri.