Arinrin-ajo mọkanla jona ku sinu ijamba ọkọ l’Ọrẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Poroporo lomije n da loju awọn eeyan ti wọn wa nibi ijamba ọkọ kan to waye niluu Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo, laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nitori bi awọn arinrin-ajo mọkanla ṣe jona ku, ti awọn ero ọkọ mi-in si tun fara pa yannayanna.

Alaye ti ẹnikan to wa nibi iṣẹlẹ ọhun ṣe fawọn oniroyin, o ni ijamba ọkọ yii waye lori afara Soka, niluu Ọrẹ, lẹyin ti awakọ ajagbe kan fi ọna tìrẹ silẹ loju ọna marosẹ naa to si ṣe bẹẹ lọọ fori sọ ọkọ bọọsi akero to n bọ lati ọna Benin, nipinlẹ Edo.

O ni loju-ẹsẹ lọkọ akero naa ti gbina, mọkanla lara awọn ero to wa ninu rẹ si jona kọja afẹnusọ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, ọga ajọ ojupopo lẹkun Ọrẹ, Ọgbẹni Sikiru Alongẹ, ni ko sẹni ti wọn ti i da mọ ninu awọn mọkanla to ba iṣẹlẹ naa rin latari bi ina ṣe jo wọn re kọja aala.

Ọgbẹni Alongẹ ni o na awọn ẹṣọ alaabo ni ọpọlọpọ wahala ki awọn too ri ina naa pa, lẹyin eyi lo ni awọn ṣẹṣẹ ṣeto bi awọn ọkọ to n gba oju ọna marosẹ ọhun yoo ṣe raaye kọja lọ sibi ti wọn n lọ.

O ni awọn ti n gbiyanju lati ko awọn ọkọ ti wọn fori sọ ara wọn kuro lọna ki igbokegbodo ọkọ le tubọ ja geere si i.

Bakan naa lo rọ awọn awakọ lati maa kiyesi awọn ofin to de irinna ọkọ fun aabo ẹmi ara wọn.

Leave a Reply