Ariwo lasan ni ofin ‘ma-fẹran-jẹko’, ko le ṣiṣẹ ni Naijiria leelae- Aarẹ Miyetti Allah

Ọlawale Ajao, Ibadan

Pẹlu bi awọn ipinlẹ kaakiri iha Guusu orile-ede yii ṣe fofin de dida maaluu jẹ oko oloko kiri, Aarẹ ẹgbẹ awọn Fulani onimaaluu, iyẹn Miyetti Allah, Ọgbẹni Abudulahi Bodejo, ti fọwọ sọya pe ariwo lasan lofin ọhun jẹ, ofin ti ko le ṣiṣẹ ni Naijiria leelae ni.

Ninu ifọrọwerọ kan ti ọga awọn Fulani darandaran yii ṣe pẹlu iweeroyin oloyinbo kan, (The Sun) lo ti sọrọ naa lopin ọsẹ yii.

O ni maaluu ati ẹran namọ ti gbogbo ọmọ orile-ede yii n pariwo pe o ti gbowo leri lasiko yii, kekere ni wọn ti i ri, nigba ti wọn ba ṣamulo ofin ma-fẹran-jẹko gan-an ni gbogbo eeyan yoo too mọ ohun ti wọn n pe ni ọwọngogo maaluu ati ẹran namọ gan-an.

Olori awọn Fulani adaranjẹ ni Naijiria yii sọ pe pẹlu bi awọn ọmọ orile-ede yii ko ṣe maa wari fun awọn Fulani ọlọsin maaluu, ki wọn si maa gbe wọn gẹgẹ yii, lati inu oṣu kọkanla, ọdun 2021 yii, ni maaluu yoo ti gbowo leri gidigidi.

Nigba to n ṣalaye idi ti eyi yoo ṣe ri bẹẹ siwaju, Ọgbẹni Bodejo fi kun un pe Fulani nikan lẹya to n jiya ju nilẹ yii nitori ti wọn ko fun wọn lanfaani lati maa da maaluu wọn jẹ kaakiri ibi to ba wu wọn, bẹẹ ni wọn ko ni ileewosan ti wọn ti le maa gbatọju pẹlu ileewe ti awọn ọmọ wọn ti le maa kẹkọọ imọ iwe.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “O ṣe ni laaanu pe ẹya Fulani nikan lawọn eeyan n di ẹbi iwa ọdaran ru lorile-ede yii, nigba ti awọn eeyan yii ki i lọwọ ninu iwa ọdaran bi tii wu ko mọ. Bii apẹẹrẹ, awọn fijilante lo n yinbọn pawọn Fulani ni ipinlẹ Sokoto gẹgẹ bíi afurasi agbebọn, bẹẹ wọn kì í ṣe agbebọn, ounjẹ ni wọn fẹẹ lọọ ra.

“Awọn ipinlẹ kan wa lapa Ariwa orileede yii, paapa ju lọ ni Zamfara, Katsina ati Sokoto, to jẹ pe niṣe lawọn Fulani maa n bẹru lati jade ra ounjẹ nibẹ nitori ti ko si aabo to peye fun ẹmi wọn lawọn agbegbe yii, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan oun wọnyi ki i ṣe ọdaran.”

O ni nibi ti nnkan de duro yii, awọn Fulani ti ṣetan lati jawọ ninu ipa ti wọn n ko lori idagbasoke orileede yii nitori, ni bayii, awọn ti ṣetan lati fi Naijiria silẹ lọ si awọn orilẹ-ede ilẹ Afrika bii Cameroon, Central African Republic ati bẹẹ bẹẹ lọ. Nigba naa lawọn ọmọ Naijiria yóò tóo mọ iyì àwọn nigba ti maaluu ati ẹran namọ ba di ọwọn gogo bio goolu.

Leave a Reply