Ariyanjiyan bẹ silẹ laarin ọmọọṣẹ Ajimọbi ati agbẹjọro lori ẹni ti yoo jẹ Olubadan tuntun

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin ti Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji, ti waja lọjọ Aiku, Sannde, oṣe yii, gbogbo aye lo ti mọ pe igbakeji rẹ, Sẹnetọ Lekan Balogun, nipo ọba kan bayii, ṣugbọn pẹlu gbogbo awọn nnkan to n lọ labẹlẹ bayii, o

ṣee ṣe ki baba naa ma le depo Olubadan gẹgẹ bii ireti gbogbo aye.

Lọjọ keji ti Ọba Adetunji tẹri gbaṣọ, iyẹn lọjọ Aje, Mọnde, lagba agbẹjọro kan, Amofin Michael Fọlọrunṣọ Lana, to tun ti figba kan jẹ kọmiṣanna fọrọ ofin ati eto idajọ nipinlẹ Ọyọ lasiko iṣejọba Gomina Adebayọ Alao-Akala, kọ lẹta si Ẹnjinia Ṣeyi Makinde ti i ṣe gomina ipinlẹ yii lati ma ṣe ti i kanju fi Sẹnetọ Balogun to ti n foju sọna funpo ọba joye naa.

Ninu awijare amofin yii, o tọka si ẹjọ ti Balogun atawọn agba oloye Ibadan mi-in pe ijọba ipinlẹ Ọyọ ta ko yiyọ ti Gomina Makinde yọ wọn kuro nipo ọba. Ṣe lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun 2017, nijọba ipinlẹ yii, laye Gomina Abiọla Ajimọbi, fawọn mọkanlelogun to ga ju lọ ninu awọn agba ijoye Ibadan jọba lori agbegbe ti wọn bi kaluku wọn si, ṣugbọn ti Gomina Makinde paṣẹ pe ki wọn gbagbe lori ọrọ ọba jijẹ naa. ki awọn le ribi pari ija ti ọrọ ọba jijẹ yii da silẹ laarin wọn pẹlu Ọba Adetunji, eyi to ti di ohun ti wọn n tori ẹ gbera wọn lọ si kootu.

Eyi ko dun mọ awọn ijoye naa ninu, ni wọn bá gba kootu lọ, wọn pe ijọba lẹjọ, wọn ni kile-ẹjọ paṣẹ fun gomina lati da awọn pada sipo ọba ti awọn ti wa ko too jẹ gomina.

Ẹjọ ti awọn eeyan yii pe ijọba l’Amofin Lana n pakiesi Gomina Makinde si, o ni bo ba fi awọn eeyan to pe ijọba lẹjọ wọnyi jọba, niṣe loun naa yoo tun da wahala mi-in silẹ, tọrọ naa yoo tun di ohun ti wọn yoo maa tori ẹ pera wọn lẹjọ lẹyinwa ọla.

O ni, Nnkan meji lo wa nibẹ, akọkọ ni ki awọn agba ijoye wọnyi gbe ẹjọ ti wọn pe ijọba kuro ni kootu, ki wọn ṣẹṣẹ waa jọ jokoo yanju ọrọ to wa nilẹ yii.

Ọna keji ni ki wọn duro de idajọ yoowu ti ile-ẹjọ ba gbe kalẹ lori ọrọ yii. Bi ile-ẹjọ ba ta ko ọba ti awọn agba ijoye wọnyi jẹ, a jẹ pe gbogbo wọn ni wọn lẹtọọ lati jẹ Olubadan niyẹn. Ṣugbọn tile-ẹjọ ba fara mọ ọba ti wọn ti jẹ tẹlẹ, a jẹ pe wọn ko lẹtọọ lati jẹ Olubadan mọ niyẹn nitori eeyan ki i jọba kan ko tun tun ọba mi-in jẹ.”

Nigba to n ṣapejuwe bi Oloogbe Ajimọbi ṣe fawọn agba ijoye ilẹ Ibadan jọba nigba naa lọhun-un gẹgẹ bii igbesẹ to lodi sofin ati ilana ilẹ Ibadan, ninu ifọrọwọrọ to ṣe pẹlu akọroyin ALAROYE lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, Amofin Lana waa gba Gomina Makinde nimọran lati ma ṣe fi ikanju yan Olubadan tuntun, ko ma ti ipa bẹẹ lugbadi ofin.

 

Ṣugbọn olori awọn oṣiṣẹ gomina lasiko iṣejọba Oloogbe Ajimọbi, Ọmọde Gbade Ojo, ta ko awijare naa, o ni ko si ohun to buru ninu igbesẹ ti Gomina tẹlẹ ọhun gbe.

Nigba ti oun naa n gbalejo ALAROYE lọfiisi ẹ, Ọmọwe Ọjọ sọ pe “Iṣẹ aje lasan l’Amofin Lana n ṣe, ko sẹni to le di Sẹnetọ Balogun lọwọ lati jẹ Olubadan nitori gbogbo igbesẹ to yẹ labẹ ofin l’Oloogbe Ajimọbi gbe ko too fi baba naa pẹlu awọn agba ijoye yooku jọba nigba naa lọhun-un.

Leave a Reply