Ariyanjiyan bẹ silẹ lori ọrọ Baba Ijẹṣa

Faith Adebọla, Eko

Bi igbẹjọ ṣe n tẹsiwaju ni kootu lori ẹjọ ti gbajugbaja adẹrin-in poṣonu nni, Ọlanrewaju James Omiyinka, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa, ni ariyanjiyan ti n ṣẹlẹ laarin awọn ololufẹ rẹ atawọn ti wọn ko nifeẹ ohun ti ọkunrin naa ṣe. Bawọn alatilẹyin rẹ ṣe n sọ pe oṣere naa yoo bọ ninu wahala naa lawọn kan n wo o pe nje oṣere yii yoo bọ ninu galagala ofin to de e yii. Bẹẹ lawọn mi-in si n sọ pe finni ladiẹ toko eemọ bọ lọrọ oṣere naa yoo ri nigbẹyin. Eyi ko sẹyin awọn ẹrin ti awọn alatako n gbe kalẹ niwaju adajọ ati ọrọ ti awọn ẹlẹrii n sọ.

Ọmọbinrin ọmọọdun mẹrinla ti wọn loṣere tiata naa fipa ba laṣepọ ti ṣalaye biṣẹlẹ naa ṣe waye, o ni kọkọrọ mọto ni Baba Ijẹṣa fi gba ibale oun ni gba toun wa lọmọọdun meje, ko too tun fọwọ pa oun lara nigba toun di ọmọọdun mẹrinla yii.
Ọrọ yii jẹ yọ l’Ọjọruu ọsẹ yii, ninu fidio kan ti ọkan lara awọn ẹlẹrii olupẹjọ, Abilekọ Ọlabisi Ajayi-Kayọde, ṣafihan rẹ nile-ẹjọ to n gbọ ẹsun akanṣe ati iwa ọdaran abẹle, eyi to wa n’Ikẹja, ipinlẹ Eko, nibi ti wọn gbọ ẹjọ afurasi ọdaran onitiata naa.

Abilekọ Ajayi-Kayọde ti kọkọ sọ ṣaaju pe ọjafafa loun nidii iṣẹ iwadii ati itọpinpin ẹsun to kan awọn ọmọde, oun si niwee-ẹri ijọba, oun ni ọga agba ileeṣẹ Cece Yara Foundation, ilu oyinbo loun ti kẹkọọ bi wọn ṣe n tuṣu desalẹ ikoko iru awọn ọrọ bii eyi.

O ni itọpinpin toun ṣe ni bonkẹlẹ pẹlu ọmọbinrin ti wọn ṣe baṣubaṣu ọhun fihan pe loootọ niṣẹlẹ naa waye, o lọmọbinrin naa ṣalaye bo ṣe jẹ.

Nigba ti agbẹjọro Baba Ijẹṣa, Amofin Babatunde Ọgala, bẹrẹ si i da ibeere bo ẹlẹrii olupẹjọ yii lobinrin naa fa fidio yọ, adajọ si gba a laye lati ṣafihan ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu ọmọbinrin naa.

Ninu fidio ọhun, ọmọbinrin naa ṣalaye pe lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹrin, ọdun yii, Ijẹṣa wa sile alagbatọ oun, iyẹn Abilekọ Damilọla Adekọya, ti inagijẹ rẹ n jẹ Madam Princess.

“Nigba tawọn eeyan ti jade, Baba Ijẹṣa kọkọ ṣe bii ẹni to n gba ipe lori foonu ẹ, bẹẹ lo n lọọ yẹ ilẹkun yara kọọkan wo lati mọ boya awọn eeyan wa nile. Ẹyin naa lo sun mọ mi, o ni ‘Ọmọ to dun ni ẹ o, bebi mi, ṣe o ni bọifurẹndi,’ mo dahun pe rara, mi o ni, lo ba fesi pe ‘nigba to o ti ni boifurẹndi yẹn, ti o dẹ tun ti waa dagba daadaa bayii, o ti di temi niyẹn o, emi ni bọifurẹndi ẹ.’

O (Baba Ijẹṣa) tun sọ pe ‘Ṣe o mọ pe mo maa n kọ ẹ ni ọpọ nnkan nigba to o ṣi kere,’ mo bi i pe ‘bii kinni yẹn o,’ tori mo fẹ ko sọrọ ki n le fi foonu mi ka ohun rẹ silẹ, foonu mi wa labẹ pilo keekeekee to wa lori aga ta a fi jokoo, mo ro pe o maa ṣalaye ohun to ṣe fun mi lọdun meje sẹyin ni, ṣugbọn ko sọ ọ, emi naa o si ri ohun rẹ ka silẹ bi mo ṣe fẹ.

O ni ‘ṣe o ti gbagbe bemi pẹlu ẹ ṣe maa n ṣere ni, ti mo maa n kọ ẹ lawọn nnkan tori pe o ṣi kere, emi ati ẹ ti ni adehun o.’ Lẹyin igba naa lo ni ki n waa jokoo le oun ni itan, ṣugbọn mo ni rara, lo ba ni ‘ṣ’ẹru waa n ba ẹ ni, o o ṣaa bẹru nigba to o ṣi kere, nisinyii ti o ti dagba daadaa yii lẹru wa n ba ẹ,’ lo ba ni ki n lọọ ba oun bu omi wa, nigba ti mọ lọ si kiṣinni, o tẹle mi lọ, asiko yii ni mama mi, awọn ọkunrin mi-in ati awọn oṣiṣẹ to so kamẹra aṣofofo CCTV, wọle.”

Abilekọ Ajayi-Kayọde tun ṣafihan ibi ti ọmọbinrin naa ti sọrọ nipa ẹsun ti wọn fi kan Baba Ijẹṣa nigba to ṣi wa lọmọ ọdun meje, o lọmọbinrin naa sọ pe lọjọ akọkọ, Baba Ijẹṣa waa ki Madam Princess ti ara ẹ ko ya nigba yẹn, o loun n wo tẹlifiṣan lọwọ ni palọ awọn, oun jokoo si ilẹẹlẹ, Baba Ijẹṣa jokoo sori aga timutimu, lo ba pe oun pe koun waa jokoo le oun lẹsẹ, oun si ṣe bẹẹ, o ni koun bọ pata oun, lo ba yọ nnkan ọmọkunrin ẹ jade, o ni koun maa fi idi rin in mọlẹ daadaa.

Ọmọbinrin naa ni nigba to ya, oun ri i pe nnkan kan n tutu mọ oun labẹ, afurasi ọdaran naa si fi ankaṣifu rẹ nu un kuro, o ni koun naa lọọ tun ara ṣe, oun si lọọ fi towẹẹli nu kinni naa kuro lara oun ni baluwẹ.

Lọjọ keji, Baba Ijẹṣa tun wa, o ba alagbatọ mi ra eso wa, ni wọn ba ni ki n tẹle e lọọ ko awọn eso naa wa ninu mọto to gbe wa, ori ijooko ẹyin ọkọ lo ko wọn si, oun si ti wọle siwaju ọkọ, o ṣilẹkun ẹyin fun mi, bi mo ṣe bẹrẹ lati maa ko awọn eso naa, niṣe lo ki kọkọrọ mọto ọwọ ẹ bọ mi loju ara, o bẹrẹ si i fi kọkọrọ naa re mi lara, lo ba tun fẹẹ kiisi mi, Ko sẹnikan nibẹ ju awa meji naa lọ. Mi o si tun foju mi kan an latigba naa ju eyi to ṣe lẹyin ọdun meje yii.”

Nigba ti wọn bi Abilekọ Ajayi-Kayọde pe bawo lo ṣe mọ pe ootọ lọrọ tọmọbinrin naa sọ, o ni awọn ibeere toun bi i ko lọju-pọ, ibeere taarata ni wọn. O tun loun ko awọn bebi tọkọ-taya meji fọmọ naa ko le fi ṣapejuwe bi iṣẹlẹ naa ṣe waye gan-an, ọmọbinrin naa si gbe bebi naa lori ẹsẹ ekeji ẹ, lati fi ṣapejuwe.

Ṣa, adajọ ile-ẹjọ akanṣe naa, Abilekọ Oluwatoyin Taiwo, ti sun igbẹjọ to ku siwaju.

Madam Princess ati ọrẹ rẹ, Iyabọ Ojo, toun naa jẹ irawọ oṣere, wa ni kootu naa lati wo bi igbẹjọ ṣe n lọ, bẹẹ ni Baba Ijẹṣa atawọn mọlẹbi rẹ wa nibẹ pẹlu.

Leave a Reply