Ariyanjiyan bẹrẹ lori idajọ iku ti wọn fun Sharif-Aminu, ọkunrin ti wọn lo bu Anọbi ni Kano

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Lati irọlẹ ana, ọjọ Aje, Mọnde, ti kootu Sharia kan niluu Kano ti dajọ iku fun Yahaya Sharif-Aminu ti wọn lo bu Anọbi Muhammad ni ariyanjiyan ti n waye lori igbesẹ ile-ẹjọ naa.
Sharif-Aminu, ẹni ọdun mejilelogun, ni wọn fẹsun kan pe o sọrọ aidaa si Muhammad ninu orin kan to gbe si ikanni intanẹẹti Whatsapp loṣu kẹta, ọdun yii.
Lẹyin ti ọkunrin naa gbe orin ọhun jade lawọn kan lọọ kọlu ile mọlẹbi rẹ, wọn si ba a jẹ gidigidi, ṣugbọn oun funra ẹ ti fara pamọ. Nigba tọwọ awọn ẹṣọ agbofinro Hisbah tẹ ẹ ni wọn wọ ọ lọ si kootu, nibi ti ko ti yi ọrọ rẹ pada.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ lanaa, Onidaajọ Khadi Aliyu Muhammad Kani ni loootọ ni olujẹjọ naa sọrọ ṣakaṣaka si Anọbi Muhammad to jẹ aṣaaju ẹsin Musulumi, iku lo si tọ si i fun iru iwa ibajẹ bẹẹ. Ṣugbọn o ni ọkunrin naa lanfaani si ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ti ko ba fara mọ eyi toun gbe kalẹ.
Sharif-Aminu jẹ atẹle ikọ Tijjaniya ati ọmọ ẹgbẹ Faidha to gba pe Ibrahim Nyass to jẹ ọmọwe kan lati ilẹ Senegal lagbara ju Muhammad lọ, eyi lo si fi huwa to ṣakoba fun un yii.
Latigba ti idajọ naa ti waye lawọn eeyan ti n sọ oriṣiiriṣii ọrọ, bi awọn kan si ṣe gba pe idajọ ika ati ọdaju ni kootu Sharia n gbe kalẹ lawọn kan sọ pe nnkan to tọ si ọkunrin naa loju ẹ ri.

2 thoughts on “Ariyanjiyan bẹrẹ lori idajọ iku ti wọn fun Sharif-Aminu, ọkunrin ti wọn lo bu Anọbi ni Kano

Leave a Reply