Arọọda ojo ṣọsẹ l’Ekiti, o ba ọpọlọpọ dukia jẹ

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ko din ni ogun eeyan lara awọn olugbe ilu Ado-Ekiti, to ti di alainile-lori bayii nitori ojo nla kan to rọ niluu naa l’Ọjọbọ, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Ojo nla ọhun bẹrẹ lalẹ ọjọ Iṣẹgun, o si rọ di idaji ọjọ keji ti i ṣe Ọjọruu. Ojo ọhun wo ile, o si tun ba awọn dukia olowo iyebiye miiran jẹ niluu naa.

Awọn ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ si ju ni awọn lanlọọdu to wa ni adugbo Dalemọ, Adebayọ ati Ọnala, niluu Ado-Ekiti, nibi ti agbara ojo yii ti kọ lu ile ti ko din ni mẹwaa, to si tun ba awọn dukia ati oun eelo ile ti ko din ni ẹgbẹlẹgbẹ milọnu naira jẹ.

Ọkan lara awọn ti ojo nla yii ba ohun ini wọn jẹ to ba ALAROYE sọrọ, Ọgbẹni Blessing Ọladele sọ pe agbara ojo naa to wa lati agbegbe ileewe girama Christ School, ni adugbo Fajuyi, lo dapọ mọ omi kan to wa lagbegbe naa ti wọn n pe ni Elemi, eyi to wa ni oju ọna to lọ si ilu Iworoko-Ekiti, eyi lo ran agbara yii lọwọ to fi lagbara pupọ, to si wo ile awọn to n gbe agbegbe naa.

Bii ile mẹwaa ni wọn ni omi yii wọ, ti ko ba jẹ pe awọn eeyan tete sare jade ni, ijamba naa iba gba ẹmi wọn.

Ọkunrin naa ni, “Yato si pe ojo naa wo awọn ile, a tun padanu dukia bii ohun eelo to n lo ina, aṣọ bẹẹdi foomu, aga ijokoo, rọọgi atawọn ohun eelo idana ninu ile.

” Ijọba Gomina Kayọde Fayẹmi ṣe oju agbara yii lasiko saa rẹ akọkọ, ṣugbọn idọti ti di i.”

Ọgbẹni Sunday Ojo toun naa fara gba ninu iṣẹlẹ naa waa rawọn ẹbẹ sijọba pe ki wọn ran awọn ara adugbo naa lọwọ, ki si ba wọn ṣe oju odo naa.

Alaga iṣẹlẹ pajawiri n’ipinlẹ l’Ekiti, Ajagunfẹyinti Sunday Adebomi, sọ pe ajọ oun ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ati pe awọn yoo ṣabẹwo si awọn adugbo ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.

Leave a Reply