Arọọda ojo fọpọ dukia ṣofo nipinlẹ Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade,  Akurẹ

Ọpọlọpọ dukia lo ṣegbe sinu arọọda ojo kan to rọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ati ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii lawọn apa ibi kan l’Akoko ati ilu Akurẹ ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ondo.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹta lojo nla ọhun bẹrẹ n’Ikarẹ Akoko, to si rọ fun bii wakati mẹrin gbako ko too da.

Ọpọlọpọ odo to wa niluu ọhun lo kun akunya, leyii to ṣokunfa bi omi ṣe bo awọn ile, ṣọọsi ati otẹẹli mọlẹ.

Pupọ awọn arinrin-ajo to n gba oju ọna marosẹ Ikarẹ si Agbaluku-Akoko ni wọn ko raaye kọja, ṣe lawọn mi-in fi ọkọ wọn silẹ loju ọna ti wọn si lọọ wa ibi sun mọju ọjọ keji ki wọn too tẹsiwaju ninu irinajo wọn.

Bakan naa lọmọ ṣori niluu Akurẹ to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo lọjọ Abamẹta, Satide, pẹlu bi omiyale ṣe tun fi ọpọ dukia ṣofo lawọn agbegbe bii Alagbaka, Ẹyin-Ala ati Ararọmi.

Adari ẹka to n mojuto ọrọ ayika nijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, Abilekọ Yẹmisi Adeniyi, ṣalaye fun akọroyin wa pe ki i ṣe igba akọkọ niyi ti iru nnkan bẹẹ n waye lawọn agbegbe kan niluu Ikarẹ.

O ni ọdọọdun lawọn eeyan maa n padanu dukia olowo iyebiye latari omiyale to saaba maa ṣọṣẹ lasiko ojo, ti ko si ti i sọna abayọ si iṣoro atigbadegba naa titi di ba a ṣe n sọrọ yii.

Abilekọ Adeniyi ni o digba tawọn araalu ba jawọ ninu kikọ ile di oju agbara ati eti odo ki iru ajalu bẹẹ too dinku lawujọ.

Leave a Reply