Arun Iba Lassa ṣeku pa alaboyun kan l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Oludamọran pataki fun gomina ipinlẹ Ọṣun lori ọrọ ilera, Dokita Ọlaṣiji Ọlamiju, ti kegbajare fun gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati ṣọra gidigidi lasiko yii ti arun iba Lassa n fẹju bii ina alẹ.
Lasiko to ṣe ilanilọyẹ lori arun yii lọ si ọja Oluọdẹ, niluu Oṣogbo, ni Ọlamiju ṣalaye pe o ti di eeyan mẹtadinlaaadoje (127) to ti lugbadi arun naa lorileede Naijiria.

O ni arun to n ti ara eku jade naa ti mu ẹmi alaboyun kan lọ bayii nipinlẹ Ọṣun.
Iwadii Alaroye fi han pe lati ipinlẹ Ondo ni alaboyun naa ti lugbadi arun yii, ko too di pe o wa sipinlẹ Ọṣun, to si jade laye.
O ni ohun to ṣẹlẹ naa ka ijọba lara pupọ, idi si niyi ti wọn fi bẹrẹ ilanilọyẹ to lagbara kaakiri ipinlẹ Ọṣun lati dena itankalẹ arun naa.

O kilọ fawọn araalu lati ma ṣe ṣi ounjẹ wọn silẹ ki eku ma baa fẹnu ba a. O ni ki wọn ri i pe ayika wọn wa ni imọtoto loorekoore, ki omi wọn si mọ tonitoni.

Ọlamiju sọ siwaju pe ki awọn eeyan ma ṣe faaye gba eku lati maa ba wọn gbe, ki wọn tete pa wọn danu, ki wọn si tete da ounjẹ ti wọn ba fura pe eku ti fọwọ kan nu kiakia.

Bakan naa lo rọ awọn iyalọja lati maa fọ pọnnpọn (pots) ti wọn fi n dana daadaa; ṣaaju ati lẹyin ti wọn ba lo wọn tan.
Lara awọn ami iba Lassa, gẹgẹ bi Ọlamiju ṣe wi ni ori-fifọ, ọna ọfun didun, ara riro, aya riro, igbẹ gbuuru, ikọ hihu, inu kikan ati ọkan ririn.
O waa ke si ẹnikẹni to ba n ṣakiyesi eyikeyii lara awọn arun yii lati tete lọ si ọsibitu to ba wa lagbegbe rẹ.

Leave a Reply