Arun Korona tun pa eeyan marun-un l’Ekoo

Faith Adebọla

 Arun Koronafairọọsi to ti di ẹrujẹjẹ kari aye bayii ti tun da ẹmi eeyan marun-un legbodo nipinlẹ Eko.

Ikede atigbadegba ti ajọ to n ri si didena itankalẹ arun nilẹ wa (National Centre for Dicease Control), ṣe nipa awọn to lugbadi arun naa kaakiri orileede Naijiria l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, fihan pe ni ipinlẹ Eko nikan, ọrinlerugba o din marun-un (275) lawọn ti arun naa ṣẹṣẹ mu lọjọ naa, nigba ti ẹpa o boro mọ fawọn marun-un lara awọn to ṣi n gba itọju lọwọ.

Iṣẹlẹ yii lo sọ aropọ awọn ti arun Korona ti lu pa nipinlẹ Eko di ojilelọọọdunrun o di mẹfa (334), apapọ awọn to ti lugbadi arun naa jẹ ẹgbẹrun lọna aadọta ati ẹgbẹta o din meje (50,593).

Amọ sa o, eeyan ẹgbẹrun lọna mẹtalelogoji ati ojidinlẹgbẹta (43,560) lo ti gbadun, ti wọn si ti pada sile wọn, nigba tawọn to ku ṣi n gba itọju lọwọ kaakiri awọn ibudo iyasọtọ ati ọsibitu ti wọn ya sọtọ fun itọju arun Korona nipinlẹ ọhun.

Tẹ o ba gbagbe, ipinlẹ Eko ni itankalẹ arun Korona pọ si ju lọ lorileede yii, latigba ti ayẹwo ti fẹni akọkọ to lugbadi  arun naa han ninu oṣu keji, ọdun 2020, to kọja yii.

Leave a Reply