Arun Korona tun pa eeyan meji ni Kwara, ijọba ibilẹ mọkanla lo ti tan de

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Eeyan meji mi-in ni arun Korona tun gbẹmin wọn mọjumọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, bo ti ṣe tan ka ijọba ibilẹ mọkanla ninu mẹrindinlogun to wa nipinlẹ Kwara.

Lapapọ, awọn marundinlọgbọn ni wọn ti padanu ẹmi wọn lati igba ti arun naa ti wọ Kwara.

Awọn marun-un mi-in tun lugbadi arun naa lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, bẹẹ lawọn alaisan mẹjọ gba iyọnda lati gba ile wọn lọ.

Atẹjade kan ti Alukoro igbimọ to n mojuto arun naa, Rafiu Ajakaye, gbe sita ṣalaye pe eeyan ọgọrun ati mọkanlelaaadọrin, 171, lo ṣi ni arun naa, wọn wa nibudo tijọba ya sọtọ fun itọju wọn.

Bakan naa, awọn ijọba ibilẹ mọkanla ti ajakalẹ arun naa ti tan de ni: Ilọrin South, Ilọrin West, Ilọrin East, Offa, Ifẹlodun, Asa, Ẹdu, Oke-Ẹrọ, Irẹpọdun, Moro ati Ọyun.

Leave a Reply