Arun korona tun paayan mẹta l’Ekoo, ọtalelelọgọfa ti tun lugbadi ẹ

Faith Adebọla, Eko

Afaimọ ko ma jẹ pe arun aṣekupani buruku nni, koronafairọọsi, tun ti fẹẹ gberi nipinlẹ Eko bayii pẹlu bi ajọ to n ri si idena arun nilẹ wa, NCDC, ṣe kede pe eeyan mẹtalelọgọfa (123) lo ṣẹṣẹ lugbadi arun naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu kejila yii. Bẹẹ lo je pe eeyan mẹta larun naa da ẹmi wọn legbodo lọjọ naa.

Ninu atẹjade ti ajọ yii n fi sori atẹ ayelujara wọn lojoojumọ lati sọ ibi ti nnkan de duro nipa arun yii ni wọn ti sọ ọrọ naa di mimọ.

Wọn ni ọrinlẹrugba o le ẹyọ kan (281) ni aropọ awọn ti arun naa ṣẹṣẹ mu lọjọ Iṣẹgun yii, ipinlẹ mẹtala ni wọn ti wa, titi kan olu ilu wa Abuja, nnkan bii idaji aropọ yii lo waye nipinlẹ Eko nikan.

Bakan naa, eeyan mẹta larun naa lu pa lọjọ naa, Eko si lawọn mẹtẹẹta ti wa.

Titi di ba a ṣe n sọ yii, aropọ ẹgbẹrun mẹtalelogun, irinwo o le mẹwaa (23,410) lo ti lugbadi arun koronafairọọsi l’Ekoo latigba ti arun naa ti bẹ silẹ ni Naijiria, ẹgbẹrun mejilelogun, ojilelọọọdunrun ati mẹta (22,342) lo ti gbadun, ti wọn si ti pada sile wọn, nigba ti okoolerugba ati mẹta (223) ko rọgbọn da si i, iku yọwọ wọn lawo ni.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu keji, ọdun yii, ni wọn kọkọ kede pe ẹnikan ni arun naa lara l’Ekoo, oyinbo ọmọ orileede Italy kan ni.

Leave a Reply