Asiko Buhari yii ti pada daye Abacha – Wọle Ṣoyinka lo sọ bẹẹ 

Aderounmu Kazeem

Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka ti sọ pe aye ijọba Sanni Abacha lawọn ọmọ Naijiria tun ti pada si bayii pẹlu bi awọn ṣoja ṣe n kọlu araalu tio ko ṣẹ wọn, ti wọn si n gbebọn fun wọn, ti ọpọ ẹmi ti ṣofo.

Ninu ọrọ to sọ jade lanaa ode yii lo ti sọ pe iwa oluko patapata gbaa ni ijọba hu lori bo ṣe ko awọn ṣoja lọọ kọlu awọn ọdọ orilẹ-ede yii ti wọn n ṣewọde kiri, ti ọpọ ẹmi si ba iṣẹlẹ naa lọ.

O lohun to foju han bayii ni pe niṣe ni ijọba fi awọn ologun rọpo ẹṣọ agbofinro SARS tawọn eeyan orilẹ-ede yii sọ pe awọn ko fẹ mọ.

Ọjọgbọn yii fi kun un pe, “Ninu iwadii ti mo ṣe, ki i ṣe pe Gomina Babajide Sanwo-Olu ranṣe pe awọn Ṣoja, bẹẹ ni ko sọ pe agbara oun ko ka eto iṣakoso Eko mọ, ohun gbogbo ti daru mọ oun lọwọ. Dajudaju, ijọba apapọ lo lo ọwọ agbara le awọn eeyan lori, laibikita agbako ati ibanujẹ ayeraye le ko ba wọn.

“Ohun ibanjẹ lo jẹ nigba ti mo gbọ tawọn eeyan kan n sọ pe iwọde ifẹhonu han yii, niṣe lo n koba ọrọ aje.”

Ọjọgbon yii sọ pe, ni gbogbo asiko ti arun koronafairọọsi (COVID 19) se awọn eeyan mọle fun odidi oṣu mẹjọ, ki lo de ti awọn eeyan wọnyi ko ṣe fi ibọn yanju ọrọ naa. O ni dajudaju, ẹmi eeyan lo dun-un fi ibọn gba, ti inu wọn yoo si maa dun pẹlu wi pe awọn ti rẹyin ọta awọn.

Wọle Ṣoyinka ti sọ pe ohun tawọn olori ilu ni lo lasiko yii ki i ṣe aṣẹ konile-gbele, bikoṣe pe ki ijọba pe ipade si gbọngan nla kan lati yanju ọrọ to wa nilẹ yii, ko si pese eto aabo fawọn eeyan to n ṣe ilu le lori. Siwaju si i, o lo yẹ ki wọn ko awọn ṣọja kuro laarin ilu, ki kaluku wọn pada si bareke wọn.

Bakan naa lo ba awọn ti wọn padanu eeyan wọn ati dukia kaaanu, to si gba ijọba niyanju lati ṣeto ‘gba ma binu’ fun wọn.

Ṣoyinka ni o yẹ ki awọn ṣoja bọ sita lati tọrọ aforiji lọwọ araalu, paapaa lọwọ gbogbo eeyan agbaye, nitori wọn ko ni awijare kankan, awọn gan-an ni wọn yinbọn pa awọn araalu ti wọn ko gbe ohun ija kankan lọwọ.

 

Leave a Reply