Asiko ti to kijọba apapọ fun awọn Amọtẹkun lanfaani lati gbe ibọn – TOM

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ẹgbẹ kan to n ja fun ẹtọ araalu, The Osun Mastermind (TOM), ti ke sijọba apapọ orileede yii lati fọwọ si lilo awọn nnkan ija ogun fun ikọ ẹṣọ alaabo Amotẹkun lati le fopin si iwa ọdaran nilẹ Yoruba.

Nibi ifọrọwerọ oloṣooṣu ti ẹgbẹ naa ṣe niluu Oṣogbo laipẹ yii ni Alakooso wọn, Dokita Wasiu Oyedokun-Alli, ti tẹnumọ ọn pe Amọtẹkun ti kun awọn ọlọpaa lọwọ lọpọlọpọ igba lati ṣeto aabo fun ẹmi ati dukia awọn eeyan iha naa latigba ti wọn ti da a silẹ.

Oyedokun-Alli ṣalaye pe “A fẹẹ da ohun (voice) wa papọ mọ ohun ti pupọ awọn lookọlookọ nilẹ Yoruba n sọ pe kijọba apapọ fun awọn Amọtẹkun lanfaani lati maa lo awọn nnkan ija gẹgẹ bo ṣe wa fun awọn ẹṣọ alaabo yooku bii tiwọn lawọn apa ibi kan lorileede yii.

“Bi ko ṣe si awọn ọlọpaa ipinlẹ, iṣẹ takuntakun ni awọn Amọtẹkun ti ṣe lati ran awọn ọlọpaa lọwọ lẹnu iṣẹ wọn lori eto aabo to peye fun ẹmi ati dukia awọn araalu, nitori naa, fifun wọn lanfaani lati gbe ibọn, lẹyin ti wọn ba ti ṣedanilẹkọọ lori lilo rẹ fun wọn, yoo tun ran wọn lọwọ lati ṣẹgun awọn ọdaran.

“A ko lero pe o yẹ kijọba da wahala aisi eto aabo to n waye bayii da awọn olopaa nitori pe wọn ko ni oṣiṣẹ to to, bẹẹ ni wọn ko ni awọn ọgbọn atinuda iru eyi ti awọn Amọtẹkun ni.”

TOM ke si awọn ọlọpaa atawọn oṣiṣẹ alaabo to ku nipinlẹ Ọṣun lati tete wa nnkan ṣe si ọrọ iwakusa lọna aitọ to ti n ran kalẹ yii ko too di pe yoo da wahala nla silẹ.

“A ti ri bi iwakusa lọna aitọ ṣe n gbilẹ kaakiri awọn agbegbe kan nipinlẹ Ọṣun. Bi eleyii ṣe ti da ipaya silẹ lawọn agbegbe naa lo tun le ṣatọna fun wahala aisi eto aabo to peye nipinlẹ yii.

“Iwadii ti fihan pe bi awọn afurasi kan ṣe n wọnu ipinlẹ Ọṣun lojoojumọ lo fa a ti awọn awakusa lọna aitọ yii fi n pọ si i. Ṣe lawọn eeyan yii maa n dira, ti wọn si maa n da wahala silẹ, eyi si le sọ wọn di afemiṣofo siluu.

“Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun gbọdọ ji giri si ojuṣe wọn lati ri i pe aisi eto aabo to n waye lọwọlọwọ bayii ko di nnkan nla ti apa ko ni i ka mọ. A ko gbọdọ fọwọ lẹran ki awọn awakusa lọna aitọ yii fa awọn Boko Haram atawọn ISWAP wọ ipinlẹ Ọṣun.

Leave a Reply