Asiko ti to lati ṣe atunto iṣejọba Naijiria, ki nnkan too daru ju bayii lọ-Falana

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Gbajugbaja amofin agba ilẹ Naijiria nni, Fẹmi Falana, ti sọ pe asiko ti to lati ṣe atunto iṣejọba ilẹ yii, ki nnkan too daru kọja atunṣe latari gbogbo rogbodiyan to n fa ipinya lojoojumọ.

Falana sọrọ ọhun lasiko to n ṣe idanilẹkọọ kan to pe akọle ẹ ni ‘Atunto ati itusilẹ Naijiria’ nibi ayẹyẹ ikẹkọọ-jade kẹrinlelogun ti Fasiti Ekiti, iyẹn Ekiti State University (EKSU), ṣe lọsẹ to kọja.

Amofin agba naa sọ pe atunto tawọn eeyan n pariwo ki i ṣe lati pin Naijiria si ẹlẹyamẹya, bi ko ṣe lati lo dukia orilẹ-ede yii fun ipinlẹ kọọkan lọna to tọ. O ni awọn ti ọrọ ko ye lo n sọ pe ẹya kan daa ju ekeji, ti wọn si n gbin inunibini sọkan awọn olugbe ilẹ yii.

Falana ni oriṣiiriṣii nnkan lo wa ninu ofin ọdun 1999 ti Naijiria n lo, ṣugbọn tawọn alaṣẹ ko ṣamulo nitori imọ-tara-ẹni-nikan to ti wọ wọn lẹwu.

O ni, ‘‘Nigba tawọn oyinbo da awọn ẹya to pada di Naijiria yii papọ lọdun 1914, awọn asọyepọ kan waye nigba naa, eyi lo si fa awọn ofin ti wọn ṣagbekalẹ titi di tọdun 1999. Ipinlẹ kọọkan lo ni awọn anfaani to yẹ ko wa sọdọ wọn latọdọ ijọba apapọ, awọn gomina wa si lagbara ju nnkan ti wọn n lo lọ.

‘‘Fun apẹẹrẹ, gbogbo awọn gomina lo wa ninu igbimọ to n dari ileeṣẹ ọlọpaa ati eto aabo, ṣugbọn ariwo Abuja lawọn eeyan maa n pa lori eto aabo to mẹhẹ nipinlẹ kọọkan. Aarẹ ilẹ yii, ọga ọlọpaa ati gbogbo awọn gomina ipinlẹ mẹrindinlogoji ta a ni ni wọn wa ninu igbimọ to n dari ileeṣẹ ọlọpaa, ṣugbọn wọn ki i ṣe ipade, koda, wọn ko ṣepade kankan ri.

‘‘Awọn gomina lagbara lati pe fun iwadii lori ileeṣẹ ijọba kan to ba kowo jẹ, wọn si le fi dandan le e fun Aarẹ lati gbe awọn igbesẹ kan. Bakan naa ni wọn lanfaani si owo tijọba apapọ ba gba pada lọwọ awọn to kowo jẹ bii Abacha, ṣugbọn ko si nnkan to jọ ọ ni Naijiria.’’

Falana tun sọ ọ di mimọ pe awọn orilẹ-ede bii Rwanda, South Afrika ati Ethiopia mu igbesẹ gbigbe awọn obinrin sipo nla lọkun-un-kundun, ṣugbọn Naijiria ko bikita nipa eleyii, eyi si lo fa bi ipinlẹ Gombe ati Cross Rivers ṣe kọ lati sọ awọn obinrin meji kan di adajọ agba.

O waa ṣekilọ pe ti awọn gomina ko ba tete gbe igbesẹ to yẹ nilana ofin lori agbara ti wọn ni, ọrọ Naijiria le bẹyin yọ laipẹ pẹlu bi gbogbo nnkan ṣe n daru lojoojumọ, ti gbese si n pọ si i.

Bakan naa ni Emir kẹrinla tilu Kano, Muhammad Sanusi, to tun jẹ olori (Chancellor) Fasiti Ekiti, sọ pe awọn ti ko mọ itumọ atunto ni wọn n fi ọrọ ẹya ati ẹsin gbe e, eyi lo si n da rogbodiyan silẹ.

Sanusi to tun jẹ ọga-agba banki apapọ banki ilẹ yii tẹlẹ ni, ‘‘Ilu Kano ni wọn bi mi si, Musulumi si ni mi, ṣugbọn lati ọmọ ọdun mẹjọ ni baba mi ti mu mi lọ sileewe awọn Katoliiki. Lati ibẹ ni mo ti lọ si King’s College, niluu Eko, bẹẹ lo jẹ pe Eko ni mo gbe ni gbogbo igba ti mo n ṣiṣẹ ni banki.

Ẹmir tẹlẹ naa ṣalaye pe ẹya Yoruba ati Ibo lo pọ ju ninu awọn ọrẹ oun, Kristẹni si ni ọpọ wọn, bẹẹ lo jẹ pe ọmọ Kano lo yọ oun kuro nipo Emir, eyi to tumọ si pe ko sẹni ti ko le ṣeeyan nijamba.

O ni lọjọ ti wọn yọ oun nipo yii, ọrẹ oun kan to jẹ ọmọ ipinlẹ Delta lo ṣeto ẹronpileeni to gbe oun lọ siluu Eko, lẹyin gbogbo wahala tijọba Kano si fi oun ṣe, awọn ọrẹ wọnyi lo ran oun lọwọ lati bẹrẹ igbesi-aye tuntun niluu Eko.

Oun naa waa ṣekilọ lori ipo ti Naijiria wa ati ọjọ ọla, bẹẹ lo pe fun igbesẹ to lagbara lai fi akoko ṣofo mọ.

Leave a Reply