Ile-ẹjọ ko-tẹmi-lọrun agba lawọn Adeyinka Oyekan gba lọ taara ki wọn le le Musẹndiku Adeniji Adele kuro lori oye ti wọn fi i jẹ gẹgẹ bii Ọba Eko. Wọn ni awọn oloṣelu ti wọn fara mọ ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa ti fi i joye o, ṣugbọn ko ni i de Iga Idunganran ti i ṣe aafin ọba lati maa paṣẹ, nitori Iga Idunganran ti gbogbo Ọba Eko maa n duro si yii, ti awọn ọmọ Dosunmu ni, bẹẹ Adele ti wọn fi jọba ki i ṣe ọmọ Dosunmu, ki ile-ẹjọ le e danu lọna aafin. Ki wọn too roju raaye pe ẹjọ yii ẹwẹ, Adeniji Adele ti ja ilẹkun aafin wọle, oun si ti wa nibẹ gẹgẹ bii ọba, wọn ti le gbogbo awọn janduku ti wọn fẹẹ dena de e danu, oun si ti wa ni Iga to n paṣẹ bi ọba.
Ohun ti Adeyinka Oyekan waa fẹ fun Adele ni ki ile-ẹjọ ba oun le e, bi ile-ẹjọ ba ti le le e, eyi to ku, iregbe ni, awọn yoo mọ bi awọn yoo ṣe le oun naa kuro laafin to ko si.
Ọrọ yii ni wọn bẹrẹ si i fa ni tọsan-toru, ti Eko si n rọ gilagila, ti ariwo Adeyinka Oyekan si gba igboro kankan, pe oun lo gbe Ọba Eko lọ sile-ẹjọ. Ọrọ naa daa titi digba ti awọn oloṣelu ko ti i bẹrẹ, ṣugbọn nigba ti eto oṣelu bẹrẹ pẹrẹu ni 1952, ti agbara si bọ si ọwọ awọn Action Group ati Ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa, nigba to si jẹ lara wọn ni Musẹndiku Adeniji Adele i ṣe, gbogbo atilẹyin to yẹ ni wọn ṣe foun, ti wọn si duro ti i titi de ipari. Nigba ti wọn dajọ naa ni Naijiria ti ko tẹ Oyekan lọrun, nitori wọn da Adele lare, o tun gbe ẹjọ naa lọ si ile-ẹjọ to ga ju lọ nigba naa to wa ni London, o ni ki wọn da ẹjọ ti wọn da ni Naijiria nu, pe ipo Ọba Eko ko tọ si Adele, bẹẹ ni ile to wa yẹn ki i ṣe ile to yẹ ko wa ko ti maa paṣẹ. Ni 1953 lo lọ si ile-ẹjọ ti London yii o, ṣugbọn nigba naa, awọn alagbara oṣelu ni West wa lẹyin Adele gbagbaagba.
Nigbẹyin, ninu oṣu kẹfa, ọdun 1957, ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu naa gan-an, wọn dajọ ni London, wọn si da Adeniji Adele lare. Wọn ni niwọn igba to ti le jẹ lẹyin iku Falolu to jọba l’Ekoo, oun Musẹndiku Adeniji Adele ni awọn afọbajẹ mu, ti wọn si fi i jọba gẹgẹ bii ilana ati aṣa Eko, ko si ibi meji ti yoo gbe ju Iga Idunganran lọ, nigba to ṣe pe ibẹ ni awọn ti wọn ti n jọba lati ọjọ yii n gbe, lati ori Dosumu, titi de Falolu to waja, ko si ohun to le fa a ti Adeniji Adele ko fi ni i gbe inu aafin. Awọn ara ilu oyinbo yii ni niwọn igba ti awọn ọba loriṣiiriṣii ti jẹ lẹyin Dosunmu, ti kaluku si n tun aafin yii ṣe bo ba ti de, ile naa ko ṣee pe ni ile Dosunmu tabi ti awọn ọmọ rẹ nikan mọ, o ti di ile awọn Ọba Eko, ẹni yoowu to ba si ti jọba l’Ekoo, ile ti yoo maa gbe niyẹn, Iga Idunganran ni ile Ọba, ki i ṣe ile awọn ọmọ Dosunmu mọ.
Bẹẹ ni ẹjọ naa pari, ẹjọ to ka Adeyinka Oyekan lọwọ ko, to na an ni wahala, to si sọ ọ lẹnu gidi. Isọnu naa pọ debii pe awọn eeyan ko fẹẹ gbọ orukọ rẹ nidii ọrọ Ọba Eko mọ, wọn ni ọbayejẹ to mura lati ba nnkan jẹ nitori ko le fi tipatipa joye ni. Ohun to si fa a ti ọrọ oye rẹ ṣe le koko diẹ ree lẹyin ti Adeniji Adele waja ni 1964. Gbogbo awọn ti wọn le dide si ọrọ naa ni wọn dide si i, wọn n sọ pe Ọba Eko yii ko tọ si Oyekan, nitori ki i ṣeeyan daadaa. Wọn ko sọ pe nitori ọrọ to ti wa nilẹ ni o, wọn kan n sọ pe ki i ṣe eeyan daadaa ni. Bẹẹ nitori ọrọ to ti wa nilẹ tẹlẹ ni, ọrọ naa lo fa a ti awọn ọta fi pọ fun un lasiko ti oun naa fẹẹ jọba, ti wọn ni oun naa ti ṣe bẹẹ fẹni kan ri. Bi ọrọ naa iba ti ṣe le to ṣaa, ija to wa ninu ẹgbẹ Action Group igba naa ko jẹ ko le to bẹẹ rara.
Egbẹ Action Group ti daru, wọn ti fọ ẹgbẹ si meji, tabi si mẹta. Awọn kan wa ti wọn ti ya lọ si ẹyin Ladoke Akintọla ti i ṣe olori ijọba Western Region, wọn si ti da ẹgbẹ Dẹmọ silẹ ni tiwọn, ẹgbẹ Dẹmọ yii lo ku to n paṣẹ ni Western Region, bo si tilẹ jẹ pe Eko jẹ ti ijọba apapọ nigba naa, awọn ijọba West naa ni agbara tiwọn. Eyi fun Oyekan ni agbara diẹ, nigba to jẹ ọrẹ rẹ, Nnamdi Azikiwe, ni aarẹ Naijiria, to si tun jẹ ọrẹ rẹ naa ni olori ijọba, iyẹn Tafawa Balewa, deede ni ohun gbogbo n lọ fun un lai ni wahala kankan. Nidii eyi, bi wọn ti fa ọrọ naa si ọtun ti wọn fa a sosi to, nigba to di ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu keji, ọdun 1965, wọn kede Adeyinka Oyekan bii Ọba Eko, wọn si gbe lẹta iyanni-sipo rẹ le e lọwo, n loun naa ba sọko ọrọ ranṣẹ si awọn ti ko fẹ ko dọba, o ni oju ti wọn wayi, ohun ti wọn ro pe ko ṣee ṣe ti ṣee ṣe, oun di ọba Eko loju wọn.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, 1965 yii, ni Oyekan funra ẹ ti kede pe oun yoo gbade oun, bi ko ba ti si idiwọ kankan mọ. Ṣe ara ti n ha ọba naa, o si ti fẹẹ maa paṣẹ laafin. Ṣugbọn igba ti awọn Oloye Bajulaye, Eletu-Odibo Eko nigba naa, ṣepade wọn, wọn ni awọn etutu ati oro ile kan wa ti wọn yoo ṣe ki ọba too le gbade, ati pe ko si bi awọn etutu naa yoo ṣe pari laarin ọjọ mẹjọ pere. Nidii eyi, wọn dajọ pe to ba di Ọjoruu, Wẹsidee, ọjọ kẹta, oṣu kẹta, ọdun 1965, wọn yoo gbe ade kari Adeyinkan Oyekan. Ṣugbọn ko too di igba naa, awọn ẹbi ati ọrẹ ti ba Adeyinka wọ Iga Idunganran, ni ile rẹ tuntun ti yoo maa gbe gẹgẹ bii Ọba Eko. Ọjọ Satide ni wọn ṣe eleyii, ni ogunjọ, oṣu keji, ọdun naa. Lọjọ naa ni awọn ọrẹ wa kaakiri, ti wọn si fi torin tilu gbe Oyekan wọ aafin naa, lẹyin ti wọn ti fi ọpọlọpọ ọjọ tun ibẹ ṣe.
Lọjọ ti wọn n mu Oyekan wọ aafin yii, nigba ti eeyan ba ti ri awọn ti wọn tẹle e de inu Iga, yoo ti mọ awọn ti wọn jẹ ki ọrọ ọba rẹ ṣee ṣe. Awọn bi Abiọla Akerele, Abiọla Oṣodi ati awọn ọmọ ẹgbẹ Ọlọfin mi-in ni wọn tẹle e. Ẹgbẹ Ọlọfin yii si ree, ẹgbẹ ti wọn mura lati fi rọpo Ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa ni. Ẹgbẹ to fara mọ ti awọn aṣaaju Ẹgbẹ Dẹmọ ni, ẹgbẹ to koriira Awolọwọ ati iṣe rẹ ni, wọn ko si faaye gba ọmọ Action Group kankan laarin wọn, afi awọn ti wọn ba ti ba Awolọwọ ja nikan. Nidii eyi, awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni wọn ja ija fun Oyekan, ti wọn si ri i pe oun ni wọn yan bii ọba. Nigba to si jẹ bi ọrọ oṣelu ati ti ijọba ti ri nigba naa ree, to si jẹ ohun to ṣẹlẹ si oun naa ni bii ọdun mẹẹẹdogun sẹyin ree, nigba tawọn oloṣelu ti ko fẹ tirẹ wa lẹyin Adeniji Adele, ko si ohun to buru bi awọn ọta ẹgbẹ to ba oun ja nijọsi ba wa lẹyin oun.
Nibi ti inu ọba tuntun yii dun de, lati ọjọ to ti wọ inu Iga, lati ọjọ Satide yii, lo ti n jo si ilu gbẹdu ati gangan ti wọn n lu laafin. Idi naa si ni pe lojoojumọ lawọn ọrẹ rẹ lati origun mẹrẹẹrin Naijiria n rọ wa, ti wọn yoo si maa ki i ku oriire si ipo Ọba. Ijọba Western Region naa ti sare kọwe si i, Ọdẹlẹyẹ Fadahunsi to jẹ gomina fun West yii labẹ Ladoke Akintọla ni awọn ki i ku oriire. Akintọla naa ko jẹ ko pẹ to fi kọwe ẹ, bẹẹ ni gbogbo awọn ti wọn si wa ninu ijọba naa ki Kabiyesi tuntun yii ku oriire. Kia ni wọn ti tẹ itage nla si Ẹnu-Ọwa l’Aarin Gbungbun Eko, nitori nibẹ ni ayẹyẹ igbade naa yoo ti waye. Bẹẹ lo jẹ ni ọjọ kẹta, oṣu kẹta, ọdun 1965, lasiko ti ija oṣelu buruku n lọ lọwọ ni West, wọn gbe ade ka ori Adeyinka Oyekan gẹgẹ bii Ọba Eko, wọn si ṣe ayẹyẹ nla rẹpẹtẹ lati fi ki ọba tuntun naa kaabọ, nitori pẹlu ijo loun naa pada sinu aafin rẹ lati Ẹnu-Ọwa.
Bayii ni Adeyinka Oyekan de ade owo, to wọ bata ilẹkẹ, to tẹpa oje, ọjọ lọjọ naa laarin awọn ara Eko, ọjọ nla kan si lọjọ ọhun nilẹ Yoruba yikayika.