Ni ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu keji, ọdun 1965, lasiko ti ija awọn oloṣelu ilẹ Yoruba n gbona gan-an, paapaa ija laarin awọn ọmọlẹyin Awolọwọ ati Akintọla pẹlu awọn eeyan rẹ, ọjọ naa ni wọn kede Adeyinka Oyekan, gẹgẹ bii ọba ilu Eko tuntun.
Aarẹ orilẹ-ede yii igba naa, Nnamdi Azikiwe, lo fọwọ si iwe naa, iyẹn iwe to sọ Oyekan di ọba. Lati igba ti Ọba Musẹndiku Adele, si ti waja ninu oṣu keje, ọdun 1964, igba naa ni wahala ti bẹrẹ, ti awọn ọmọọba loriṣiiriṣii si ti dide, ṣugbọn ninu gbogbo awọn ti wọn dide yii, ọpọ lo dide nitori wọn ko fẹ ki Oyekan di “Oba of Lagos”, wọn ni o san ki ẹlomi-in jẹ ẹ ju ko jẹ Oyekan ni yoo di ọba le awọn lori lọ. Ọta pọ fun ọkunrin naa, awọn oloye ilu ti ko si fẹ ko jọba pọ ju awọn ti wọn fẹ ẹ lọba lọ. Ko si si ohun to fa a ju ọrọ oṣelu ati ijọba to ti wa nilẹ tẹlẹ lọ. Ija naa pọ gan-an ni.
Ohun to fa a niyi to jẹ nigba ti oniṣẹ de lati ileeṣẹ to n ri si ọrọ abẹle ni Naijiria nigba naa, iyẹn Ọgbẹni I. A. Wemambu, to si mu lẹta naa wa fun Oyekan ni ile rẹ ni Opopona Garba Square, ni bii aago marun-un kọja iṣẹju mẹwaa, ohun to kọkọ ti ẹnu ẹ jade ni, “Ọlọrun doju tẹyin ọlọtẹ!” Ṣe awọn oniroyin ti gbọ tẹlẹ, nigba ti wọn yoo si fun un ni lẹta, oju wọn lo ṣe. Bo ti gba lẹta naa lo doju kọ wọn, ohun to si sọ ni pe, “Iwe ti mo gba yii, Ọlọrun gbe mi bori gbogbo awọn oniṣẹ ibi ni. O gbe mi leke gbogbo awọn ẹni aburu. Ohun ti mo ṣe sọ bẹẹ ni pe ọmọ ọdun mẹrinla ni mo wa ti baba to bi mi ti sọ fun mi pe mo maa jọba Eko, ṣugbọn awọn kan ti wa nibi kan ti wọn ko fẹ ko ṣee ṣe. Ṣugbọn o ti ṣee ṣe loju wọn bayii, nitori iwe ti wọn gbe le mi lọwọ yii, iwe ipesiṣẹ ni, wọn ni ki n waa ṣiṣẹ fun ilu ni, ma a si ṣe e daadaa.
“Bi mo ṣe wa yii, mo ti pinnu pe n ko ni i ba oloṣelu tabi ẹgbẹ oṣelu kankan ṣe, mo fẹẹ da duro temi ni. Ṣugbọn ko sẹni to le pa ohun mọ agogo lẹnu, n oo sọ gbogbo ọrọ yoowu to ba wa lọkan mi jade, bi nnkan ba si ṣe ri ni mo ṣe maa sọ ọ. Bi emi ba sọ temi o, ohun to ba wu ijọba lo le ṣe, ṣugbọn mo maa wi tẹnu mi, bo tilẹ jẹ ijọba lo laṣẹ. Ijọba to wa lode bayii, ijọba to ṣe deede, ijọba ti ki i gbe sẹyin ẹnikan ni, o wu mi ko jẹ bi wọn ṣe maa maa ṣe e lọ naa niyẹn. Wọn ti fun mi niwee aṣẹ, wọn ti fun mi ni lẹta, bi ohun gbogbo ba si lọ bo ṣe yẹ ko lọ, ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii, ni wọn maa de fila fun mi gẹgẹ bii ọba Eko, ko sohun to tun le fa idiwọ mọ. Ọkan pataki ninu iṣẹ ti mo fẹẹ sare ṣe ni lati kọ gbagede nla kan fawọn ọdọ wa, nibi ti wọn aa ti maa ṣere, ti wọn aa maa kọ ẹkọ loriṣiiriṣii, nitori ko ti i si aaye igbafẹ kankan fun wọn laarin Eko.”
Igba naa ni Adeyinka Oyekan sọrọ pe ko si irẹpọ laarin awọn ọba Yoruba, lara iṣẹ oun si ni lati ri i pe irẹpọ de saarin awọn ọba ilẹ Yoruba gbogbo. Oyekan ni ọrọ oṣẹlu lo n da wahala awọn ọba yii silẹ, nitori ẹ loun ko ṣe ni i ba wọn da si oṣelu rara. Bi Oyekan ba sọ bayii, tabi to ba n sọrọ si awọn kan to pe ni ọta ara rẹ, o mọ idi to fi n wi bẹẹ o jare. Ori ko pe oun fẹẹ ba ọrun duro, lati di ọba fun Oyekan, irinajo ọjọ pipẹ gbaa ni, o si ni wahala gidi ninu. Ohun to si fa wahala naa ni pe Oyekan naa paapaa ti fi igba kan sun mọ awọn oloṣelu pẹkipẹki. Ọrẹ loun ati Nnamdi Azikiwe, nitori bẹẹ, ẹgbẹ oṣelu rẹ lo fi si lọdọ, ko too di ọba rara ni o, nigba to fi n ṣe iṣẹ apoogun ni Ọsibitu gbogbogboo (General Hospital). Nitori bẹẹ, oun naa ti gbojule pe ko si igbakigba ti aaye ọba ṣi silẹ, oun loun yoo jẹ ọba naa dandan.
Bo ti n ronu niyi nigba ti Ọba Falolu ku ni ọjọ keji, oṣu kẹṣan-an, ọdun 1949. Nigba naa, ọmọ ọdun mejidinlogoji ni Oyekan, o si ti ṣiṣẹ o ti lowo, o si ti ro pe ko si ohun ti ko ni i jẹ ki oun di ọba Eko, paapaa pẹlu atilẹyin ẹgbẹ NCNC, ẹgbẹ to lagbara gan-an nilẹ Yoruba, ati ni Naijiria nigba naa. Awọn aṣaaju NCNC naa ti mura silẹ, wọn si ni ko si wahala fun un, yoo di ọba Eko yii ni. Ṣugbọn ọmọọba kan wa to n jẹ Musẹndiku Adeniji Adele, ọmọ ọdun mẹrindinlọgọta loun ni 1949 yii, iyẹn ni pe o fi ọdun mejidinlogun ju Adeyinka Oyekan lọ. Yatọ si eyi, ọkan pataki ninu awọn ọmọ ẹgbẹ Oduduwa ti Ọbafẹmi Awolọwọ da silẹ ni, bẹẹ naa lo si jẹ alatilẹyin ẹgbẹ ọdọ Naijiria, ‘Nigeria Youth Movement’, ọkan ninu awọn aṣaaju wọn l’Ekoo ni. Yatọ si eyi, oṣiṣẹ ijọba Eko ni, o si lẹsẹ, bẹẹ lo lẹnu daadaa ju Oyekan lọ.
Bi a ba ti yọwọ agbara ati atilẹyin ẹgbẹ oṣelu ti Oyekan n reti nigba naa, ko si bo ṣe le duro lẹgbẹẹ Musẹndiku Adele, nitori ẹni ti ọpọ eeyan mọ ni, ẹni to si ti ṣe oriṣiiriṣii nnkan meremere si Eko nigba ti ko tilẹ ti i di ọba wọn ni. Ọpọ ẹgbẹ awọn ara Eko lo jẹ oun ni baba isalẹ fun wọn, awọn mi-in si wa to jẹ oun gan-an lo da wọn silẹ fun ilọsiwaju Eko, lati igba ti oun naa ko ti ju ọmọ ọgbọn ọdun lọ lo ti wa lẹnu akitiyan bẹẹ, to si ṣe e titi to fi n lọ si bii ọgọta ọdun. Nitori bẹẹ, ọpọ eeyan foju si i lara pe oun ni Ọba Eko tọ si. Ṣugbọn boya nitori pe baba tiẹ ti sọ fun un nigba to wa lọmọ ọdun mẹrinla pe yoo jọba Eko, tabi ti awọn olosẹlu ti wọn n ti i lẹyin, Oyekan nigbagbọ pe asiko toun niyẹn, oun si gbọdọ di ọba naa dandan ni. N lo ba bẹrẹ si i ṣa awọn eeyan jọ, kia loun naa si ti lero lẹyin, ti awọn naa n sọ pe oun n 0i ipo ọba tọ si.
Awọn NCNC naa n rin si i, wọn o duro rara, ṣugbọn awọn ọmọ ẹgbẹ Oduduwa, ati awọn alatilẹyin wọn nigba naa ti wọn jọ jẹ ojulowo ọmọ Yoruba, ti wọn si lagbara gidi niwaju ijọba oyinbo rin si ọrọ Adele naa, lọjọ gan-an ti ọkunrin naa si fẹyinti ninu iṣẹ ijọba ni wọn kede ẹ bii Ọba Eko, wọn si gbe ade le e lori lọjọ keji. Ọgbọnjọ, oṣu kẹsan-an, 1949, nirọlẹ, ni wọn kede rẹ, asiko si ti kọja ti ẹnikẹni le gba ile-ẹjọ lọ, bi ilẹ si ti n mọ ni ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa, ni wọn de fila ọba fun un. N lo ba di ọba Eko, ọrọ naa jo ẹgbẹ oṣelu NCNC lara, ati Oyekan ti wọn n ti lẹyin, nitori awọn ko mọ pe ọna ti wọn yoo gba yọ si awọn niyẹn. Wọn ti ro pe bi ọjọ Mọnde kan ni wọn yoo kede orukọ ẹni ti wọn ba fẹẹ fi jọba, wọn si ti mura silẹ pe to ba ti le jẹ Adele ni, awọn n gba ile-ẹjọ lọ lati gbegi dina pe wọn ko gbọdọ sọ ọ dọba Eko rara.
Nigba ti ọrọ waa ri bayii, awọn NCNC ati Oyekan ni awọn ko gba, wọn ni awọn ko ni i jẹ ki Adele wọ inu aafin gẹgẹ bii ọba, wọn ni ko ni i de Iga Iduganran nitori ki i ṣe ọmọ Dosunmu, wọn ni ki wọn ma fi i jẹ ọba Eko, ko wa ibomi-in ti yoo ti jọba. Ohun ti wọn tori ẹ gbe e dele-ẹjọ ni pe ki i ṣe ọmọ Dosumu, ko le duro si Iga Iduganran, nibi ti aafin awọn ọba Eko wa. Ohun ti wọn gbojule ni pe bi ile-ẹjọ ba le da awọn lare eyi, ti wọn ni ki Adeniji Adele ma de Iga, wọn yoo ni ko yẹ ni ẹni to gbọdọ jẹ ọba Eko niyẹn, ko yaa gbe ade silẹ fun alade, a ṣe pe Oyekan ni yoo di Ọba Eko niyẹn. Bi ọrọ naa ti di wahala gidi ree, ti Oyekan pe Adele lẹjọ, ti awọn NCNC ti i lẹyin, ti wọn si n sọ pe Musẹndiku Adeniji Adele ti wọn gbe ade fun ko ni i di Ọba Eko, Adeyinka Oyekan ni yo pada di ọba.
Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.