Asiri baba to n ba iyawo ọmọ ẹ laṣepọ tu ni Ṣaki lo ba sa lọ

Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun

Ṣe ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan ni to toloun, aṣiri baba ọkọ kan, Ọgbẹni Rahmọni Abubakar, to n fọbẹ ẹyin jẹ ọmọ bibi inu rẹ niṣu ti pada tu sita, wọn ka baba agbalagba naa mọ ibi to ti n ṣe kinni fun iyawo ọmọ rẹ, Rofiat Ayinkẹ, ni otẹẹli ni Ṣaki.

Ọgbẹni Quazim Abubakar, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, to loun n ṣiṣẹ awakọ tanka epo lo sọrọ nipa iṣẹlẹ yii f’ALAROYE, o ni oun lọrọ naa ṣẹlẹ si, iyawo oun ni baba to bi oun lọọ n ba laṣepọ, Ọlọrun si ti fi awọn mejeeji foun mu.

Quazim ni oun ko tete fura si wọle wọde ọkunrin yii ati iyawo oun Rofiat Ayinkẹ, ọmọ ọdun mẹtalelogun, latari pe iyawo naa ti bimọ mẹrin foun, ibeji wa ninu awọn ọmọ ọhun, oun o si le ronu pe iru nnkan bẹẹ le maa waye laarin iyawo oun ati baba oun.

Ba a ṣe gbọ, Rọfiat ni wọn lo ti kọkọ figba kan gbe ẹjọ ọkọ rẹ lọ sileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn ọmọ orukan (Welfare) pe ki wọn ba oun gba awọn ọmọ mẹrẹẹrin to wa laarin oun ati ọkọ oun, ki oun maa da nikan tọju wọn tori oun o nifẹẹ ọkọ oun mọ, o fẹsun kan ọkọ naa pe ko ki i tọju awọn ọmọ, ko si ṣetan lati gbọ bukaata idile naa gẹgẹ bii ọkọ gidi. Aṣe lara idi ti Rọfiat fi fẹẹ kọ ọkọ ẹ ni ajọṣe to ti wa laarin oun ati baba ọkọ, wọn ni kinni baba ọkọ ẹ lo dun mọ ọn.

Ọjọruu, Wẹsidee yii, ni ọrọ bẹyin yọ nigba ti Quazim yọju si ọfiisi awọn Welfare, to lọọ fẹjọ iyawo rẹ sun. Kootu ni Quazim kọkọ fẹẹ lọ, ṣugbọn iyanṣẹlodi to n lọ lọwọ lawọn ile-ẹjọ ko jẹ ki eyi ṣee ṣe.

Wọn ni nigba ti ọkọọyawo yii debẹ, o loun fẹẹ ja iwe fun iyawo oun, oun o fẹ ẹ mọ, oun o si le pari ija pẹlu ẹ tori aṣiri ẹ ti tu soun lọwọ.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, o ni igba kan wa toun o niṣẹ lọwọ, ko si sowo lọwọ oun, ṣugbọn iyawo oun ko mọ ọn foun, asiko yii gan-an lo n fojoojumọ beere owo lọwọ oun fun oriṣiiriṣii nnkan, toun ba si fesi pe ko sowo, yoo fabinu yọ ni. Ṣugbọn iyalẹnu lo n jẹ foun biyawo oun ṣe n rowo ṣe irun ati awọn ẹṣọ meremere to n lo lasiko naa, eyi to mu ki ara fu oun.

Quazim ni lọjọ kan loun kọsẹ gbọ itakurọsọ to waye laarin baba oun ati iyawo oun lori foonu, ninu ọrọ ti wọn n sọ naa lo ti foju han pe ajọṣepọ ti wa laarin wọn, tori niṣe ni wọn fun ara wọn ni adehun lati pade ni Tuwoyin Hotel, kawọn jọ ṣe faaji.

O ni otẹẹli ti wọn pada gbe ara wọn lọ loun ka wọn mọ. Nigba ti ọrọ di ariwo laṣiiri tu pe awọn mejeeji ko ṣẹṣẹ maa ba ara wọn lo pọ, awọn eeyan si jẹrii si i pe oriṣiiriṣii otẹẹli to wa lagbegbe Ṣaki ni wọn ti n pade.

Bi akara ṣe tu sepo ni iyawo ọhun, Rọfiat, bu sẹkun, o ni ki wọn ba oun bẹ ọkọ oun, pe iṣẹ eṣu ni. O loun o fẹẹ kọ ọkunrin naa silẹ.

Ṣugbọn ọkọ ti fariga pe oun ko tun le gba ki obinrin naa wa labẹ orule oun mọ. Bẹẹ ni baba ọkọ to huwa ainitiju naa ti sa lọ, awọn agbofinro ṣi lawọn n wa a.

Leave a Reply