Atẹgun ojo ṣeku pa eeyan meji n’Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

Eeyan meji; Ibrahim Fọlarin ati Sunday Ogbonna, ni wọn padanu ẹmi wọn lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, sinu ijamba atẹgun ojo niluu Ilọrin.

Igbakeji gomina, Kayọde Alabi, to ṣe abẹwo sawọn agbegbe ti atẹgun ojo naa ti sọsẹ ba ẹbi awọn to padanu ẹmi ati dukia wọn kẹdun.

Alabi gba awọn tọrọ naa kan nimọran lati ni suuru fun ijọba, nitori pe eto ti n lọ lati ran wọn lọwọ.

Lara awọn ti atẹgun wo ile ati orule ile wọn rọ ijọba lati ba wọn tun un kọ, dipo ki wọn fun awọn ni owo.

Awọn agbegbe ti igbakeji gomina ṣabẹwo si ni, Ode Alfa-Nda, Ile Akuji, Ile Bada, Ita Ogunbọ, Ita Kudimọ, Ita Ẹgba, Idi Igba,  Sakele, Okekere, Koko Igbonna, Abata Sunkere, Oju Ẹkun, Orisan Koko.

Leave a Reply