Atẹnujẹ ko ba ọlọkada, obinrin to gbe fun un lọti mu, lo ba gbe ọkada to ṣẹṣẹ ra sa lọ

Ṣe ki Ọlọrun gba ni lọwọ atẹnujẹ ni, ẹni to ba ti n wa ifa, dandan ni ko ri ofo. Ọrọ yii lo difa fun ọkunrin ọlọkada kan ti awọn obinrin ajeji kodogbo fi nnkan mimu lọ, toun naa si sare si i bi ẹni ti ko ri iru rẹ ri. Ṣe o kuku ti ro pe ifa lo wọle tọ oun yii, ki oun yaa jifa naa ni. Afi bi ifa ṣe fa a ni apo ya, to si tori ohun mimu ti ko pe igba Naira sọ ọkada ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira to ṣẹṣẹ ra ti ko ni nọmba nu.

Oorun buruku ni atilaawi sun Iẹyin to mu ohun mimu ti wọn gbe fun un tan, nigba ti yoo si fi laju saye, ala lo kọkọ ro pe oun n la nigba ti ko ri ọkada rẹ mọ.

Ohun ti awa ri gbọ ni pe ipinlẹ Delta ni iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ. Ọmọbinrin to rẹwa kan atawọn ẹgbẹ ẹ lo pe ọlọkada naa pe ko gbe awọn lọ si otẹẹli kan ti wọn n pe ni Kenu Guest House, to wa ni Bonsaac, wọn ni awọn fẹẹ lọọ tura nibẹ.

Eyi ti ọlọkada yii yoo fi gbe wọn debẹ ti yoo gba owo iṣẹ rẹ, ti yoo si maa lọ, o jọ pe ẹwa awọn ọmọ yii lo wọ ọ loju, bi ohun mimu ti wọn si ni awọn fẹẹ ra fun un ni ko jẹ ko mọ ohun to n ṣe mọ.

N ni jagunlabi ba gbe ọkada silẹ, o tẹle awọn ẹruuku wọnu otẹẹli lati ba wọn ṣe faaji, lawọn yẹn ba gbe ọti ti wọn ti fi oogun orun ati oogun oloro si ninu fun un, wọn ni koun naa fi sara-rindin, ṣe aisi nibẹ ni aiba wọn da si i.

Atẹnujẹ to pa Sule Igbira lo ko ba ọkunrin ọlọkada ti wọn ko sọ orukọ rẹ fun wa yii. Bo ṣe mu ọti ti wọn gbe fun un tan ni jagunlabi fẹyin lelẹ, lo ba sun lọ fọnfọn.

N lawọn Aishat ba ṣina fun ọkada tuntun ti ko ti i gba nọmba si yii, ni wọn ba gbe e lọ ni tiwọn gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta, Edafe Bright,  ṣe fiṣẹlẹ naa sita.

Kantankantan bii ọmo ku lọwọ aditi lo ku ti ọlọkada n ṣe nigba to taji ti ko ri ọkada rẹ mọ, lo ba gba Eria Kọmandi wọn to wa niluu Asaba lọ lati fọrọ naa to wọn leti.

Ọga ọlọpaa ibẹ lo paṣẹ fun awọn ọmọọṣẹ rẹ pe awari ti obinrin n wa nnkan ọbẹ ni ki wọn fi ọrọ awọn olubi ẹda naa ṣe.

Bayii ni awọn ọlọpaa bẹrẹ iṣẹ iwadii, aipẹ yii si ni ọwọ tẹ ọkan ninu awọn ti wọn ṣe bii ero, ti wọn gun ọkada, ti wọn si ji ọkada naa lọ yii, Aisha Hassan.

Iwadii ṣi n tẹsiwaju lati mu awọn ẹlẹgbẹ rẹ to ku.

Leave a Reply