Atẹnujẹ ko ba Peter, nitori to n mugbo, adajọ ni ko gba’lẹ kootu fọjọ marun-un

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọdọmọkunrin kan, Peter Igwe, ladajọ kootu Majisreeti kan niluu Ileefẹ sọ pe ko gbalẹ ayika kootu fun ọjọ marun-un lori ẹsun pe o n mugbo.

Ẹsun meji ni wọn fi gbe Peter wa sile-ẹjọ, ẹsun akọkọ ni mimu igbo, ekeji ni pe o n gbe nnkan ti ofin ti de kaakiri.

Nigba to n sọrọ ni kootu, Agbefọba Emmanuel Abdullahi ṣalaye pe ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, ni olujẹjọ huwa naa lagbegbe Ita-Ooṣa, niluu Ileefẹ.

O ni nigba ti wọn ka igbo mọ ọn lọwọ, ko le ṣalaye ibi to ti ri i, eleyii to si nijiya labẹ abala ọtalelugba o din mọkanla ati ojilenirinwo o din mẹwaa ofin iwa ọdaran ti ọdun 2002 tipinlẹ Ọṣun n lo.

Nigba ti wọn beere lọwọ rẹ boya o jẹbi ẹsun mejeeji tabi ko jẹbi, olujẹjọ sọ pe oun jẹbi ẹsun akọkọ, ṣugbọn oun ko jẹbi ẹsun keji.

Adajọ A. Ayẹni da olujẹjọ lẹbi lori ẹsun kin-in-ni, nigba to da a lare lori ẹsun keji.

Fun idajọ ẹsun kin-in-ni to jẹbi rẹ ọhun, Ayẹni sọ pe ki olujẹjọ gba gbogbo ilẹ ayika kootu naa fodidi ọjọ marun-un.

Leave a Reply