Bo tilẹ jẹ pe niṣe lawọn eeyan kan n sa lati gba abẹrẹ ajẹsara lati fi gbogun ti arun koronafairọọsi, sibẹ igbakeji
Aarẹ orilẹ-ede yii tẹlẹ, Alhaji Abubakar Atiku, ti gba a niluu Dubai.
Gẹgẹ bi alaye ti Ọgbẹni Paul Ibe, ẹni ti i ṣe agbẹnusọ fun ọkunrin naa ṣe sọ, o ni oludije fun ipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, gba abẹrẹ naa l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹfa, niluu Dubai.
O fi kun un pe pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, abẹrẹ ajẹsara arun Koronafiarọọsi ọhun ṣe pataki fawọn eeyan lati gba a nilẹ adulawọ, paapaa ni Naijiria. Ati pe iyẹn gan-an lo mu Atiku gba a lati fi han awọn eeyan pe oun to dara ni.