Atiku Abubakar ki Tinubu ku oriire

Ọrẹoluwa Adedeji
Oludije funpo aarẹ lorukọ ẹgbẹ PDP, Alaaji Atiku Abubakar, ti ki Aṣiwaju Bọla Tinubu ku oriire bo ṣe jawe olubori lasiko idibo abẹle ẹgbẹ naa to waye ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Atiku ni, ‘Mo ki Bọla Ahmed Tinubu ku oriire fun bo ṣe jawe olubori gẹgẹ bii oludije funpo aarẹ lasiko idibo abẹle ẹgbẹ wọn, o ja ija gidi lori eleyii, bi o si ṣe jawe olubori fi ọkan akin ti nnkan ki i su han’.
Ninu ọrọ mi-in to sọ ni igbakeji aarẹ tẹlẹ naa ti ni ẹgbẹ oṣelu APC ko le ri ida mẹẹẹdọgbọn to pọn dandan fun ẹgbẹ oṣelu lati mu ni awọn ipinlẹ ti PDP n dari lasiko ibo ọdun 2023.
Lasiko to n ba awọn gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lorukọ ẹgbẹ naa ṣepade lo sọ eyi di mimọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, nile ẹgbẹ wọn. Nibẹ lo ti rọ awọn oludije naa pe ki gbogbo wọn fi ọja kan ṣe igbanu, ki wọn le rọwọ mu lasiko idibo ọdun to n bọ.

Leave a Reply