Atiku fẹẹ ko ẹlẹrii ọgọrun-un wa si kootu

Adewale Adeoye

Ondije dupo aarẹ orileede yii lẹgbẹ oṣelu ‘Peoples Democratic Party’ (PDP), Alhaji Atiku Abubarkar, ti rọ ileejọ to n gbo awọn ẹsun to jẹ yọ lori ibo aarẹ to waye ninu oṣu Keji, ọdun yii, pe ki wọn gba oun laaye lati fi ẹlẹrii ọgọrun mi-in kun ti tẹlẹ, kẹjọ naa le lẹsẹ nilẹ daadaa bi igbẹjọ ọhun ba ti bẹrẹ ni pẹrẹu.

Lori igbesẹ ti Alhaji Atiku gbe yii, ajọ eleto idibo nilẹ yii ‘Independent National Electoral Commission’ (INEC) naa ti rọ ileejọ ọhun pe ki wọn gba awọn paapaa laaye kawọn naa fi ẹlẹrii mejilelogun kun tawọn naa. Bakan naa ni Aṣiwaju Tinubu ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan sipo ọhun tun ni ki wọn faaye gba oun paapaa lati mu ẹlẹrii mọkandinlogoji kun ti tẹlẹ, nigba ti ẹgbẹ APC sọ pe ẹlẹrii mẹẹẹdọgbọn lawọn yoo fi kun awon to ti wa nilẹ tẹlẹ bayii.

Ninu ọro lọọya Atiku, Chris Uche SAN, lo ti sọ pe ofin ṣi faaye ọsẹ meje silẹ fawọn lati ṣawari awọn ẹlẹrii gbogbo tawọn nilo lori ẹjọ naa, ṣugbọn nitori pe oju ẹjọ ọhun ti n foju han kedere bayii, ko gbọdọ gba awọn ju ọsẹ mẹta pere lọ mọ lati pe gbogbo ẹlẹrii yoowu tawọn nilo pata wa sile-ẹjọ ọhun.

Lẹyin gbogbo atotonu awọn agbẹjọro to wa nileejọ naa, ileejọ sun igbẹjọ ọhun si ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.

Leave a Reply