Atiku gba awọn gomina nimọran:Ẹ pe ipade apero apapọ funra yin, ẹ ma duro de ijọba apapọ mọ

Faith Adebọla

 Loju ọna lati wa ojutuu siṣoro eto aabo to mẹhẹ ati awọn ipenija mi-in to n ba orileede yii finra, Alaaji Atiku Abubakar, igbakeji olori orileede wa tẹlẹ, ti sọ fawọn gomina pe niṣe ni ki gbogbo wọn fori kori lati ṣeto apero apapọ kan lati wa iyanju sawọn iṣoro wa, ki wọn ma lawọn n duro de ohun tijọba apapọ fẹẹ ṣe, ki wọn ma si ṣepade naa ni ẹlẹkun-jẹkun.

Ninu atẹjade kan to pe akọle rẹ ni: “Naijiria ti daagun, iduro o si mọ,” eyi to fi lede lọjọ Aiku, Sannde yii, lo ti sọrọ lori ero rẹ ati ọna abayọ si iṣoro aabo to gbode kan yii.

O ni niṣe ni ki gbogbo gomina ipinlẹ mẹrindinlogoji ilẹ wa fi igbanu kan ṣoṣo ṣe ọja lori ọrọ to delẹ yii, ki wọn si fi ohun kan sọrọ, dipo ti wọn yoo maa ṣẹpade ni ẹlẹkun-jẹkun, tori bii igba teeyan n fi ọwọ kan ṣoṣo patẹwọ ni ti wọn ba gbe apero naa kari ẹlẹkun-jẹkun.

Bakan naa lo ni ki wọn ma lawọn n duro de ohun tijọba apapọ fẹẹ ṣe, tabi ki wọn ro pe ijọba apapọ lo yẹ ko pe fun iru apero bẹẹ, tori ijafara lewu gidi nibi ti ọrọ de yii.

Atẹjade naa ka lapa kan pe: “Ẹ jẹ ka ta ọgbọn kan si ipenija to dojukọ wa yii. Mo rọ awọn gomina wa lati ma ṣe lawọn n duro de ki Abuja (ijọba apapọ) mu ayipada rere wa mọ, dipo iyẹn, niṣe ni ki wọn tete ṣeto apero iṣọkan apapọ eyi ti gbogbo awọn gomina pata yoo pesẹ si, ti wọn yoo si fikun lukun lori ọna abayọ si awọn ọrọ to takoko to le ṣakoba fun ọjọ ọla orileede wa, titi ti wọn aa fi ri ojuutu si i.

“Ẹ gbagbe nipa ẹgbẹ oṣelu ọtọọtọ ti kaluku yin ti wa o, ẹ gbẹ iyẹn ju sẹgbẹẹ kan, ẹ gbe ọrọ ẹlẹyamẹya naa ju sẹgbẹẹ kan, ẹ ma ki ti ọrọ ẹsin bọ ọ, bo tilẹ jẹ pe ẹ ni lati bọwọ fun ẹsin ti kaluku n ṣe, ṣugbọn ilana to daa ninu ẹsin yẹn ni kẹ ẹ mu lo. Ẹ ṣepade pọ, ẹ ba ara yin sọrọ, ẹ sọ oju abẹ nikoo, ẹ sọ ootọ gidi fun ara yin, kẹ ẹ si wa ojuutu sawọn ipenija wọnyi jade.

“Lẹyin naa ni kẹ ẹ pada sawọn ipinlẹ yii lati lọọ ba awọn aṣofin ipinlẹ ati apapọ yin sọrọ, ki wọn le ṣiṣẹ lori awọn ofin to yẹ lati fi gba awọn ojutuu tẹ ẹ wa jade nidii. Ọna ta a le gba yọ Naijiria ninu ewu yii niyẹn o.

Atiku tun ṣalaye pe bii igba teeyan n duro de oogun awogba-arun si aisan to n ṣe e, dipo ko tete maa lo ogun lọkọọkan ni ọrọ maa jẹ ti awọn gomina ba fẹẹ maa duro de ki ijọba apapọ ṣaaju tabi ki wọn lawọn fẹẹ wo igbesẹ aarẹ na, o ni nnkan yoo ti bajẹ kọja atunṣe, abamọ ki i si ṣaaju ọrọ.

O ni iṣoro nla kan ta a ni lọwọlọwọ yii ni pe “orileede yii ti daagun, ki i ṣe pe a daagun lori ọrọ oṣelu ati okoowo nikan ni, a tun daagun si ara wa lẹnikọọkan.

Mo ti maa n sọ ọ tipẹ pe iyatọ to wa laarin wa ki i ṣe ọrọ pe ara Ariwa lẹni kan, ara Guusu lẹni keji, ṣugbọn iyatọ laarin keeyan ṣe nnkan to daa ati kẹlomi-in ṣe aburu. Tori naa, niṣe ni kawọn to fẹẹ ṣe rere kora jọ lati le fi han awọn alaidaa pe a pọ ju wọn lọ, rere lo si maa ṣẹgun ibi.”

Atiku ni ki i ṣe ba a ṣe maa fọ Naijiria si wẹwẹ lo yẹ ko jẹ wa logun lasiko yii, ṣugbọn ba a ṣe maa pọkan pọ lati wa ojuutu sawọn iṣoro wa. Ta a ba pinnu lati yanju iṣoro wa, a maa yanju ẹ dandan, o si maa ṣe gbogbo wa lanfaani ju ka pin yẹlẹyẹlẹ lọ.

O ni aṣiṣe ti a ti maa n ṣe sẹyin ni ka maa ro pe ijọba apapọ lo le yanju iṣoro, a ti gbagbe pe lai si awọn ipinlẹ, ko le seeyan ni Aso Rock, eyi lo fi jẹ pe keeyan too le de Aso Rock bii Aarẹ, lati awọn ipinlẹ ni wọn aa ti dibo to pọ fun onitọhun.

“Awọn gomina wa mọ pe nnkan o rọgbọ ni Naijiria, tori ẹ ni ọkan-o-jọkan ipade ati apero fi n lọ laarin wọn. Ojuṣe ti wọn ni yii naa ni ki wọn lo lati ṣepade papọ, ki wọn si yanju gbogbo ohun to wa nilẹ yii, ki wọn ranti pe ohunkohun to ba ṣẹlẹ si Naijiria, o maa kan ọpọ orileede adulawọ nilẹ Afrika ati lagbaaye pẹlu.”

Leave a Reply