ATM lawọn eleyii fi n lu jibiti ni Festac ti EFCC fi mu wọn

Faith Adebọla, Eko

 

 

 

Ọjọ gbogbo ni t’ole, ọjọ kan ni t’olohun, ilẹ ọjọ kan ọhun lo mọ awọn marun-un kan tọwọ awọn agbofinro ṣẹṣẹ tẹ lagbegbe Festac, niluu Eko, kaadi onike ti wọn fi n gbowo lẹnu ẹrọ ATM lawọn n lu jibiti ẹ, ti wọn si fi n jale.

Awọn ọlọpaa ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu, EFCC, lo lọọ fi pampẹ ofin gbe awọn maraarun lowurọ Ọjọbọ, Tọsidee yii, ninu ile fulaati kan ti wọn mori mu si ni Festac. Orukọ wọn ni Sonny Okwaraji, Daniel C. Stephen, Sylvester Otuwa, Jeff Ogbonaya ati Nestor Ezeani.

Alukoro ajọ EFCC to jẹ k’ALAROYE gbọ nipa iṣẹlẹ yii sọ pe o ti pẹ tawọn ti n dọdẹ awọn afurasi ọdaran naa.

O ni ileeṣẹ otẹlẹmuyẹ FIB to wa lorileede Amẹrika lo mu ẹsun wa pe awọn amookunṣika ẹda kan ti ja banki igbalode kan lole owo dọla ti iye rẹ ku diẹ ko to ọtalerugba dọla Amẹrika (257,822.16 USD), lawọn ba bẹrẹ si i fimu finlẹ pẹlu imọ ẹrọ, titi tawọn fi tọpasẹ jibiti naa de ọdọ awọn afurasi ọdaran yii.

O ni kaadi ATM bii ọgọta ọtọọtọ lawọn ba lọwọ wọn loriṣiiriṣii, pẹlu kọmputa agbeletan (laptops) marun-un, wọn si ti jẹwọ pe loootọ lawọn huwa ọbayejẹ naa.

Nwajuren ni ti wọn ba ti fi kaadi naa wọ owo jade ninu akaunti awọn kọsitọma banki tan, ọtọ lawọn kaadi ti wọn aa tun lo lati fi taari owo naa sinu awọn akaunti tiwọn to wa lawọn banki mi-in, ori atẹ ayelujara si ni wọn ti n ṣe gbogbo ẹ.

Alukoro EFCC ni iwadii ṣi n lọ lọwọ, o lawọn afurasi naa ti n tanmọlẹ sawọn ohun to ṣokunkun, awọn si maa ko gbogbo de kootu laipẹ.

Leave a Reply