Atunṣe bẹrẹ nileewosan ilu Ọttẹ lẹyin aṣẹ Gomina Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Nitori ipo to buru jai tileewosan alaboyun ijọba to wa niluu Ọttẹ wa, Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq, ti paṣẹ ki wọn bẹrẹ atunṣe ibẹ ni kiakia, ọsẹ yii lo si gbera sọ.

Ileewosan ọhun, Ọttẹ Maternity and Dispensary Clinic, lo wa nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara.

Atẹjade kan ti Akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye, fọwọ si ṣalaye pe Abdulrahman paṣẹ naa lasiko to ṣabẹwo sileewosan to ti dẹnu kọlẹ ọhun lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, bẹẹ ni iṣẹ atunṣe ati rira awọn ohun eelo igbalode sibẹ

Lasiko to bẹ Ọttẹ-Ọja wo, Abdulrahman ni ijọba yoo pese omi-ẹrọ fawọn araalu to n gbe ibẹ.

Ileewosan Ọttẹ ni ikẹtadinlogoji ti gomina yoo ṣatunṣe si latigba to ti gori aleefa nitori o ni erongba oun ni lati tun gbogbo ileewosan nipinlẹ Kwara ṣe.

Alhaji Yusuf Abdul to jẹ Alangua tilu Ọttẹ gboriyin fun gomina fun awọn iṣẹ idagbasoke tijọba rẹ n dawọ le, ni pataki ju lọ, nijọba ibilẹ Asa.

Awọn fọtọ ileewosan naa niyi:

Leave a Reply