Atunto nikan lo le yanju iṣoro ti Naijiria n koju lọwọ- Gomina Akeredolu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti ni siṣe atunto nikan lo le yanju gbogbo iṣoro tawọn ọmọ orilẹ-ede yii n koju lọwọ.

Aketi fidi eyi mulẹ ninu ọrọ to bawọn eeyan ipinlẹ Ondo sọ lati fi sami ayajọ ominira to waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.

Akeredolu ni ko si ani-ani pe ọpọlọpọ aiṣedeedee lo wa ninu eto iṣejọba ti Naijiria n lo lọwọlọwọ, leyi to ṣokunfa bi gbogbo nnkan ṣe n ri rudurudu, ti iwa ọdaran si tun n fojoojumọ gbilẹ si i lawujọ.

O ni asiko yii gan-an lo yẹ kawọn ọmọ orilẹ-ede yii fimọ ṣọkan, kí wọn si jọ gbero lori ohun ti yoo jẹ ọna abayọ si gbogbo iṣoro ti awọn eeyan ilẹ yii n la kọja lọwọ.

Arakunrin ni ko sídìí to fi yẹ ki eyikeyii ninu awọn eeyan Naijiria jiya pẹlu ọpọlọpọ awọn nnkan alumọọni ti Ọlọrun fi ta ẹya kọọkan lọrẹ.

Akeredolu ni o ti to asiko to yẹ ki ijọba apapọ fun ipinlẹ kọọkan laaye ati maa ṣakoso awọn nnkan alumọọni to wa ni arọwọto wọn nitori pe awọn ajeji lasan ni wọn n ji awọn nnkan olowo iyebiye naa ko nibi tijọba tọju wọn si.

Bakan naa lo tun rọ ijọba apapọ pe ko fawọn gomina ipinlẹ kọọkan laaye lẹkun-un-rẹrẹ lati mojuto eto aabo agbegbe koowa wọn, ki nnkan le rọrun fawọn araalu.

Ni ipari ọrọ rẹ, Aketi pe awọn ọmọ ile igbimọ asofin ipinlẹ l’Abuja nija lati tun ijokoo wọn jo, ki wọn si wọna lati ṣatunṣe si ofin ọdun 1999, eyi to le jẹ ki ayipada rere tá a n fẹ tete ya kankan.

Leave a Reply