Wale Ajao, Ibadan
Awọn kan n sọ pe iyi ni fun Olubadan lati ko awọn ọba alade rẹpẹtẹ lẹyin nigba to ba n lọ sode. Iyẹn ọba to ba n lọọ tọrọ owo lọwọ aarẹ tabi gomina. Ko si Olubadan kankan to jẹ iru ijẹkujẹ bẹẹ ri ninu itan. Erongba Ajimọbi daa lori ọba to fi awọn agba ijoye jẹ, ṣugbọn ko ro atubọtan ẹ. Ko mọ pe ọrọ yẹn yoo ba aṣa Ibadan ati eto bi wọn ṣe n jọba jẹ. Ara ẹ naa lo delẹ yii. Njẹ ẹ gbọ ọ ri ninu itan pe Olubadan atawọn ijoye rẹ pera wọn lẹjọ ri bi? Ti Sẹnetọ Balogun ba jẹ Olubadan, ti awọn agba ijoye rẹ ba lọ saafin lati lọọ ṣepade pẹlu ẹ, ṣe wọn yoo dọbalẹ fun un abi wọn ko ni i dọbalẹ fun un. Gbogbo nnkan to yẹ ki Ajimọbi ro daadaa ree ko too fi awọn agba ijoye jọba. Ẹyin ẹ wo bi Olubadan ṣe waja ti awọn ijoye rẹ ko debi eto isinku ẹ. Bi wọn ba gba ọrọ ọba ti Ajimọbi fi wọn jẹ yii silẹ bẹẹ, ade ti Ajimọbi de fun wọn ko ni i jẹ ki awọn agba-ijoye yii le maa ṣe ẹyẹ ikẹyin fun Olubadan yoowu to ba jẹ.