Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori eto aabo to mẹhẹ lorileede yii, paapaa, nitori laasigbo ti ẹya ajeji n da silẹ, ti wọn n ji awọn ọmọ Yoruba gbe, ti wọn si n pa wọn nipakupa nilẹ baba wọn, awọn ẹya Itsekiri, nipinlẹ Delta, lawọn ti ṣetan lati ran iran Yoruba lọwọ.
Olori ikọ ọmọ-ogun ibilẹ ẹya Itsekiri, Oloye Ọmọlubi Newuwum lo fidi igbesẹ yii mulẹ nibi ipade apero eto aabo kan ti gbogbo agbarijọ awọn eleto aabo ibilẹ nilẹ Yoruba ṣe ninu gnọngan nla ileetura Kakanfo Inn, n’Ibadan, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla yii.
Gẹgẹ bi Oloye Ọmọlubi ṣe sọ, ‘Gbogbo wa la mọ pe awọn Fulani ati ilana ti a n gba ṣeto ijọba lorileede yii lo n dena ilọsiwaju ilẹ Yoruba, idi ree ta a ṣe gbọdọ para pọ lati sa ipa wa lati gba ara wa silẹ lọwọ awọn ọta wa.
O daa bi wọn ṣe da Amotekun silẹ nilẹ Yoruba. Awa naa da iru ẹ kan silẹ lọdọ wa ta a pe ni Agbokomasaa. Awa ta a jẹ jagunjagun ibilẹ le daabo bo ilu wa ju agbofinro ijọba apapọ lọ nitori awọn yẹn ko mọ agboole, aarin ilu ati inu igbo wa to wa”.
Apapọ awọn to kopa ninu apero nla ọhun to ẹgbẹrun meji (2,000) niye. Ninu ninu wọn la ti ri oriṣiiriṣii ikọ eleto aabo ibilẹ Yoruba bii O.P.C., Agbẹkọya, fijilate, ẹgbẹ awọn ọdẹ ibilẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Nigba to n ṣalaye idi ti wọn ṣe pejọ bẹẹ, Ọmọwe Victor Taiwo, ẹni to ṣagbatẹru ipade ọhun, ṣalaye pe nnkan mẹta lo jẹ iṣoro ẹya Yoruba, aisi eto aabo, iṣọkan ati ominira, ati pe bi ko ba si iṣọkan ati aabo, niṣe lawọn ọta yoo maa fiya jẹ ẹya Yoruba, wọn ko si ni i le ni ominira lati bọ ninu iya naa laelae.
Ninu ipade alagbara ọhun ni wọn ti gbe igbimọ majẹẹ-o-bajẹ kan kalẹ lati maa dari awọn agbofinro ibilẹ Yoruba ti wọn ko jọ wọnyi pẹlu itọju ati ipese ohun eelo ti wọn yoo maa fi koju awọn afẹmiṣofo ati oniruuru awọn ọdaran gbogbo.
Ninu igbimọ ọhun, eyi to ko gbogbo ẹka igbesi aye ọmọniyan sinu, la ti ri Oṣilẹ ti Oke-Ọna nipinlẹ Ogun, Ọba Adedapọ Tẹjuoṣo, gẹgẹ bii olori igbimọ fun ọrọ awọn lọbalọba; Ọmọwe Bayọ Orire gẹgẹ bii olori igbimọ nipa awọn oloṣelu ati ọrọ oṣelu; Aarẹ Musulumi ilẹ Yoruba, Alhaji Dauda Makanjuọla Akinọla, gẹgẹ bii alamoojuto igbimọ lori ọrọ ẹsin ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Oloye Ọmọlubi ti waa rọ awọn to gbe ipade apero naa kalẹ lati wa aaye fi awọn Itsekiri naa ninu awọn igbimọ ti wọn gbe kalẹ ọhun, nitori ọmọ Oduduwa lawọn paaapaa jẹ, nitori naa, wọn ti ṣetan lati dara pọ mọ awọn eleto aabo ilẹ Yoruba fun idaabobo awọn ọmọ iya wọn pẹlu ilẹ baba wọn.