Awa kọ la ran Ọlọfaana ni gbogbo ohun to sọ, o sọ ọ lorukọ ara ẹ ni-TAMPAN

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Latigba ti ọrọ Baba Ijẹṣa ti ṣẹlẹ, ti Iyabọ Ojo ti gba kinni ọhun kanri, lawọn eeyan ti n sọ pe awọn agba ẹgbẹ tiata Yoruba ko tilẹ sọrọ, wọn ko ṣe fidio bii tawọn mi-in ti wọn n gbe oriṣiiriṣii ọrọ jade. Ṣugbọn ni bayii, awọn agba ẹgbẹ TAMPAN, ẹka tilu Eko ti sọrọ, wọn ko sọrọ lasan lori iṣẹlẹ yii, wọn fi awọn ofin kan lelẹ, wọn si sọ ibi ti wọn duro si lori iṣẹlẹ naa ni.

Ninu fidio kan ti AKEDE AGBAYE ri, Ọmọọba Jide Kosọkọ lo n ka ero ọkan ẹgbẹ TAMPAN jade, bẹẹ ni Mista Latin to jẹ Aarẹ TAMPAN wa nikalẹ. Ọga Bello wa nibẹ, Alaaji Adebayọ Salami, Yinka Quadri ko gbẹyin, bẹẹ si ni Akeem Alimi(Ajala Jalingo) naa wa nikalẹ, ti gbogbo wọn mu ẹda iwe ti Jide Kosọkọ n ka dani.

Ohun ti wọn fi ṣide iwe naa ni bo ṣe jẹ ẹdun ọkan pe awọn eeyan tawọn agba oṣere kọ niṣẹ tiata ni ko bọwọ fawọn agba ọhun mọ, to jẹ wọn tapa si aṣa ibọwọ fagba nilẹ Yoruba, lai wo ti pe opo to gbe iṣẹ tiata Yoruba duro ni ibọwọfagba i ṣe.

TAMPAN ni awọn ko fọwọ si iwakiwa, awọn ko fọwọ si iṣekuṣe. Wọn ni bẹnikan ba huwa abuku lawujọ, ẹni ọhun lo ṣẹ, ki i ṣe kawọn eeyan awujọ ati lori ayelujara maa foju abuku wo awọn yooku ti wọn jọ jẹ ọmọ ẹgbẹ naa.

Wọn ni eyi ko tọna, awọn ko si ni i gba iru ẹ, nitori ika to ba ṣẹ lọba n ge.

Lori ibi ti wọn duro si lori ọrọ Baba Ijẹṣa, awọn TAMPAN sọ pe awọn ko ni i sọ ohunkohun lori ẹ mọ, ko si saaye fun ẹnikẹni lati maa jade sọrọ lorukọ ẹgbẹ.

Wọn ni awọn ti fa ọrọ naa le kootu lọwọ, nitori ẹgbẹ to bọwọ fun ofin lawọn. Ẹgbẹ sọ pe ibi ti kootu ba da a si naa lawọn n ba ile-ẹjọ lọ, ẹgbẹ awọn ki i tẹ ofin loju, awọn n bọwọ fofin ni.

Nigba to n ṣalaye siwaju lori ọrọ ti agba oṣere nni, Alagba Adedeji Aderẹmi (Ọlọfa ina) sọ ni kootu l’Ọjọbọ to kọja nipa awọn obinrin onitiata ati Iyabọ Ojo, Ọmọọba Jide Kosọkọ sọ pe TAMPAN kọ lo ran baba naa lati sọ ohun to sọ.

O ni Ọlọfa ina sọrọ gẹgẹ bii ẹni kan ṣoṣo ni, ki i ṣe gẹgẹ bii ẹgbẹ. O ni ero ọkan baba naa lo sọ. Loootọ, o le binu nitori bo ṣe ni Iyabọ ba oun sọrọ, ṣugbọn iyẹn ko sọ pe ẹgbẹ lo ran baba niṣẹ. Ati pe keeyan maa lero pe wọn fidi gba roolu (ipa) ninu ere ko ri bẹẹ, o ni beeyan ba ṣe mọṣẹ ọhun si, bo ṣe ni ifọkansin to, ati idaniloju lo n jẹ keeyan riṣẹ gba, ki i ṣe dandan ka bara ẹni sun ka too fun ni niṣẹ ṣe. Bi takọ-tabo to ti balaga ba jọ gba pe awọn fẹẹ maa ba ara awọn ni nnkan pọ, Jide Kosọkọ sọ pe iyẹn ko kan ẹgbẹ, ipinnu awọn eeyan naa ni. O ni ṣugbọn ko sibi kan ninu iwe ofin ẹgbẹ awọn to sọ pe afi kobinrin mẹyin lelẹ ko too gba roolu o.

Awọn Iyabọ Ojo ati Nkechi Blessing ti wọn si sọ ara wọn di arijagba nitori ọrọ Baba Ijẹṣa, ẹgbẹ TAMPAN ni o dun awọn pe awọn eeyan to ti jere ẹgbẹ, ti wọn ti fiṣẹ tiata ṣe nnkan ire lo wa nidii iwa abuku, wọn ni ṣugbọn lati isinyii lọ, ẹnikẹni to ba tapa sawọn ofin ẹgbẹ bo ṣe wa lakọsilẹ, iya to tọ si tọhun yoo jẹ ẹ ni, ko si awitunwi asan kan nibi kan.

Leave a Reply